Luk 19

19
Jesu ati Sakiu
1JESU si wọ̀ Jeriko lọ, o si nkọja lãrin rẹ̀.
2Si kiyesi i, ọkunrin kan wà ti a npè ni Sakeu, o si jẹ olori agbowode kan, o si jẹ ọlọrọ̀.
3O si nfẹ lati ri ẹniti Jesu iṣe; kò si le ri i, nitori ọ̀pọ enia, ati nitoriti on ṣe enia kukuru.
4O si sure siwaju, o gùn ori igi sikamore kan, ki o ba le ri i: nitoriti yio kọja lọ niha ibẹ̀.
5Nigbati Jesu si de ibẹ̀, o gbé oju soke, o si ri i, o si wi fun u pe, Sakeu, yara, ki o si sọkalẹ; nitori emi kò le ṣaiwọ ni ile rẹ loni.
6O si yara, o sọkalẹ, o si fi ayọ̀ gbà a.
7Nigbati nwọn si ri i, gbogbo wọn nkùn, wipe, O lọ iwọ̀ lọdọ ọkunrin ti iṣe ẹlẹṣẹ.
8Sakeu si dide, o si wi fun Oluwa pe, Wo o, Oluwa, àbọ ohun ini mi ni mo fifun talakà; bi mo ba si fi ẹ̀sun eke gbà ohun kan lọwọ ẹnikẹni, mo san a pada ni ilọpo mẹrin.
9Jesu si wi fun u pe, Loni ni igbala wọ̀ ile yi, niwọnbi on pẹlu ti jẹ ọmọ Abrahamu.
10 Nitori Ọmọ-enia de lati wá awọn ti o nù kiri, ati lati gbà wọn là.
Òwe Nípa Owó Wúrà
(Mat 25:14-30)
11Nigbati nwọn si ngbọ́ nkan wọnyi, o fi ọ̀rọ kún u, o si pa owe kan, nitoriti o sunmọ Jerusalemu, ati nitoriti nwọn nrò pe, ijọba Ọlọrun yio farahàn nisisiyi.
12O si wipe, Ọkunrin ọlọlá kan rè ilu òkere lọ igbà ijọba fun ara rẹ̀, ki o si pada.
13 O si pè awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ mẹwa, o fi mina mẹwa fun wọn, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã ṣowo titi emi o fi de.
14 Ṣugbọn awọn ọlọ̀tọ ilu rẹ̀ korira rẹ̀, nwọn si rán ikọ̀ tẹ̀le e, wipe, Awa kò fẹ ki ọkunrin yi jọba lori wa.
15 O si ṣe, nigbati o gbà ijọba tan, ti o pada de, o paṣẹ pe, ki a pè awọn ọmọ-ọdọ wọnni wá sọdọ rẹ̀, ti on ti fi owo fun nitori ki o le mọ̀ iye ere ti olukuluku fi iṣowo jẹ.
16 Eyi ekini si wá, o wipe, Oluwa, mina rẹ jère mina mẹwa si i.
17 O si wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere: nitoriti iwọ ṣe olõtọ li ohun kikini, gbà aṣẹ lori ilu mẹwa.
18 Eyi ekeji si wá, o wipe, Oluwa, mina rẹ jère mina marun.
19 O si wi fun u pẹlu pe, Iwọ joye ilu marun.
20 Omiran si wá, o wipe, Oluwa, wò mina rẹ ti mbẹ li ọwọ́ mi ti mo dì sinu gèle:
21 Nitori mo bẹ̀ru rẹ, ati nitoriti iwọ ṣe onrorò enia: iwọ a ma mu eyi ti iwọ ko fi lelẹ, iwọ a si ma ká eyi ti iwọ kò gbìn.
22 O si wi fun u pe, Li ẹnu ara rẹ na li emi o ṣe idajọ rẹ, iwọ ọmọ-ọdọ buburu. Iwọ mọ̀ pe onrorò enia ni mi, pe, emi a ma mu eyi ti emi ko fi lelẹ emi a si ma ká eyi ti emi ko gbìn;
23 Ẽha si ti ṣe ti iwọ ko fi owo mi si ile elé, nigbati mo ba de, emi iba si bère rẹ̀ ti on ti elé?
24 O si wi fun awọn ti o duro leti ibẹ̀ pe, Ẹ gbà mina na lọwọ rẹ̀, ki ẹ si fi i fun ẹniti o ni mina mẹwa.
25 Nwọn si wi fun u pe, Oluwa, o ni mina mẹwa.
26 Mo wi fun nyin pe, Ẹnikẹni ti o ni, li a o fifun; ati lọdọ ẹniti kò ni, eyi na ti o ni li a o gbà lọwọ rẹ̀.
27 Ṣugbọn awọn ọtá mi wọnni, ti kò fẹ ki emi ki o jọba lori wọn, ẹ mu wọn wá ihinyi, ki ẹ si pa wọn niwaju mi.
28Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o lọ ṣaju, o ngòke lọ si Jerusalemu.
29O si ṣe, nigbati o sunmọ Betfage on Betaní li òke ti a npè ni Olifi, o rán awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀,
30Wipe, Ẹ lọ iletò ti o kọju si nyin; nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ọ lọ, ẹnyin o ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan ti a so, ti ẹnikẹni ko gùn ri: ẹ tú u, ki ẹ si fà a wá.
31 Bi ẹnikẹni ba si bi nyin pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ntú u? ki ẹnyin ki o wi bayi pe, Oluwa ni ifi i ṣe.
32Awọn ti a rán si mu ọ̀na wọn pọ̀n, nwọn si bá a gẹgẹ bi o ti wi fun wọn.
33Bi nwọn si ti ntú ọmọ kẹtẹkẹtẹ na, awọn oluwa rẹ̀ bi wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ntú kẹtẹkẹtẹ nì?
34Nwọn si wipe, Oluwa ni ifi i ṣe.
35Nwọn si fà a tọ̀ Jesu wá: nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹ̀hin ọmọ kẹtẹkẹtẹ na, nwọn si gbé Jesu kà a.
36Bi o si ti nlọ nwọn tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na.
37Bi o si ti sunmọ eti ibẹ̀ ni gẹrẹgẹrẹ òke Olifi, gbogbo ijọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bẹ̀rẹ si iyọ̀, ati si ifi ohùn rara yìn Ọlọrun, nitori iṣẹ nla gbogbo ti nwọn ti ri;
38Wipe, Olubukun li Ọba ti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa: alafia li ọrun, ati ogo loke ọrun.
39Awọn kan ninu awọn Farisi li awujọ si wi fun u pe, Olukọni ba awọn ọmọ-ẹhin rẹ wi.
40O si da wọn lohùn, o wi fun wọn pe, Mo wi fun nyin, Bi awọn wọnyi ba pa ẹnu wọn mọ́, awọn okuta yio kigbe soke.
Jesu Sọkún Lórí Jerusalẹmu
41Nigbati o si sunmọ etile, o ṣijuwò ilu na, o sọkun si i lori,
42O nwipe, Ibaṣepe iwọ mọ̀, loni yi, ani iwọ, ohun ti iṣe ti alafia rẹ! ṣugbọn nisisiyi nwọn pamọ́ kuro li oju rẹ.
43 Nitori ọjọ mbọ̀ fun ọ, ti awọn ọtá rẹ yio wà yàra ká ọ, nwọn o si yi ọ ká, nwọn o si ká ọ mọ́ niha gbogbo.
44 Nwọn o si wó ọ palẹ bẹrẹ, ati awọn ọmọ rẹ ninu rẹ; nwọn kì yio si fi okuta kan silẹ lori ara wọn; nitoriti iwọ ko mọ̀ ọjọ ìbẹwo rẹ.
Jesu Lòdì sí Lílo Tẹmpili Bí Ọjà
(Mat 21:12-17; Mak 11:15-19; Joh 2:13-22)
45O si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o si bẹ̀rẹ si ilé awọn ti ntà ninu rẹ̀ sode;
46O si wi fun wọn pe, A ti kọwe rẹ̀ pe, Ile mi yio jẹ ile adura; ṣugbọn ẹnyin ti sọ ọ di ihò olè.
47O si nkọ́ni lojojumọ ni tẹmpili. Ṣugbọn awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn olori awọn enia nwá ọ̀na ati pa a run,
48Nwọn kò si ri bi nwọn iba ti ṣe: nitori gbogbo enia ṣù mọ́ ọ lati gbọ̀rọ rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Luk 19: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀