Mat Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé tí à ń pè ní Ìyìn Rere Matiu ni ó fún wa ní ìròyìn ayọ̀, pé Jesu ni Olùgbàlà tí Ọlọrun ti ṣe ìlérí. Òun ni Ọlọrun lò láti mú àdéhùn tí Ọlọrun bá àwọn eniyan inú Majẹmu Laelae dá ṣẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láàrin àwọn Juu ni wọ́n ti bí Jesu, ìyìn rere yìí kì í ṣe fún àwọn Juu nìkan; ti gbogbo aráyé ni.
Létòlétò ni wọ́n kọ Ìwé Matiu. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìtàn ìbí Jesu, lẹ́yìn náà ó sọ nípa bí ó ṣe gba ìrìbọmi ati bí èṣù ṣe dán an wò. Ó tún sọ nípa iṣẹ́ waasu ati ti ìkọ́ni ati ti ìwòsàn tí Jesu ṣe ní Galili. Lẹ́yìn náà, ìwé ìyìn rere yìí sọ nípa ìrìn àjò Jesu láti Galili títí dé Jerusalẹmu. Ó tún sọ nípa àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jesu láàrin ọ̀sẹ̀ tí ó kẹ́yìn ìgbé-ayé rẹ̀. Boríborí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ọ̀sẹ̀ náà tí a kọ sinu ìwé yìí ni nípa ìkàn-mọ́-àgbélébùú ati ajinde rẹ̀.
Ìwé Ìyìn Rere yìí júwe Jesu pé Olùkọ́ni pataki ni, ati pé ó ní àṣẹ láti túmọ̀ òfin Ọlọrun, ó sì kọ́ni nípa ìjọba Ọlọrun. Ìwé yìí pín àwọn ẹ̀kọ́ tí Jesu kọ́ni sí ọ̀nà marun-un. Ó tò wọ́n ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí gẹ́gẹ́ bí oríṣìí ẹ̀kọ́ tí wọ́n jẹ́. (1) Ọ̀kan ni iwaasu lórí òkè, tí ó sọ nípa ìwà àwọn ọmọ ìjọba Ọlọrun, iṣẹ́ wọn, àwọn anfaani tí wọn ní, ati àtubọ̀tán wọn (orí 5 títí dé 7); (2) Ìlànà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila nípa iṣẹ́ wọn (orí 10); (3) Àwọn òwe nípa ìjọba ọ̀run (orí 13); (4) Ẹ̀kọ́ nípa ìtumọ̀ jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn (orí 18); (5) Ẹ̀kọ́ nípa òpin àkókò tí a wà yìí, ati bíbọ̀ ìjọba Ọlọrun (orí 24—25).
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Àkọsílẹ̀ Àtìrandíran Jesu Kristi ati ìbí rẹ̀ 1:1—2:23
Àwọn ohun tí Johanu Onítẹ̀bọmi ṣe 3:1-12
Ìrìbọmi Jesu ati ìdánwò rẹ̀ 3:13—4:11
Iṣẹ́ tí Jesu ṣe ní gbangba ní Galili 4:12—18:35
Láti Galili dé Jerusalẹmu 19:1—20:34
Ọ̀sẹ̀ ìkẹyìn Jesu ní Jerusalẹmu ati ní agbègbè rẹ̀ 21:1—27:66
Ajinde Oluwa ati bí ó ṣe farahàn káàkiri 28:1-20
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Mat Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.