Mik 1
1
1Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Mika ara Moraṣti wá li ọjọ Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda, ti o ri niti Samaria ati Jerusalemu.
Ìpohùnréré Ẹkún nítorí Samaria ati Jerusalẹmu
2Ẹ gbọ́, gbogbo ẹnyin enia; fetisilẹ, Iwọ ilẹ aiye, ati ẹkún rẹ̀: si jẹ ki Oluwa Ọlọrun ṣe ẹlẹri si nyin, Oluwa lati inu tempili mimọ́ rẹ̀ wá.
3Nitori, wo o, Oluwa jade lati ipò rẹ̀ wá, yio si sọ̀kalẹ, yio si tẹ̀ awọn ibi giga aiye mọlẹ.
4Awọn oke nla yio si yọ́ labẹ rẹ̀, awọn afonifojì yio si pinyà, bi ida niwaju iná, bi omi ti igbálọ ni ibi gẹ̀rẹgẹ̀rẹ.
5Nitori irekọja Jakobu ni gbogbo eyi, ati nitori ẹ̀ṣẹ ile Israeli. Kini irekọja Jakobu? Samaria ha kọ? ki si ni awọn ibi giga Juda? Jerusalemu ha kọ?
6Nitorina li emi o ṣe Samaria bi òkiti pápa, ati bi gbigbin àjara: emi o si gbá awọn okuta rẹ̀ danù sinu afonifojì, emi o si ṣi awọn ipalẹ rẹ̀ silẹ.
7Gbogbo awọn ere fifin rẹ̀ ni a o run womu-womu, gbogbo awọn ẹbùn rẹ̀ li a o fi iná sun, gbogbo awọn oriṣà rẹ̀ li emi o sọ di ahoro: nitoriti o ko o jọ lati inu ẹbùn panṣaga wá, nwọn o si pada si ẹbùn panṣaga.
8Nitori eyi li emi o ṣe pohunrere, ti emi o si ma hu, emi o ma lọ ni ẹsẹ lasan, ati ni ihòho: emi o pohunrere bi dragoni, emi o si ma kedaro bi awọn ọmọ ògongo.
9Nitori ti ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ alailewòtan; nitoriti o wá si Juda; on de ẹnu-bode awọn enia mi, ani si Jerusalemu.
Ọ̀tá Súnmọ́ Jerusalẹmu
10Ẹ máṣe sọ ni Gati, ẹ máṣe sọkun rara: ni ile Afra mo yi ara mi ninu ekuru.
11Ẹ kọja lọ, iwọ ará Safiri, pẹlu itiju rẹ ni ihòhò: ara Saanani kò jade wá; ọ̀fọ̀ Beteseli yio gba iduro rẹ̀ lọwọ nyin.
12Nitori ara Maroti nreti ire, ṣugbọn ibi sọkalẹ ti ọdọ Oluwa wá si ẹnu bode Jerusalemu.
13Iwọ ara Lakiṣi, di kẹkẹ mọ ẹranko ti o yara: on ni ibẹrẹ ẹ̀ṣẹ si ọmọbinrin Sioni: nitori a ri irekọja Israeli ninu rẹ.
14Nitorina ni iwọ o ṣe fi iwe ikọ̀silẹ fun Moreṣetigati: awọn ile Aksibi yio jẹ eke si awọn ọba Israeli.
15Sibẹ̀ emi o mu arole kan fun ọ wá, Iwọ ara Mareṣa: ogo Israeli yio wá si Adullamu.
16Sọ ara rẹ di apari, si rẹ́ irun rẹ nitori awọn ọmọ rẹ ẹlẹgẹ́; sọ apári rẹ di gbòro bi idì; nitori a dì wọn ni igbèkun lọ kuro lọdọ rẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Mik 1: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.