Mak 2
2
Jesu Wo Arọ Sàn
(Mat 9:1-8; Luk 5:17-26)
1NIGBATI o si tún wọ̀ Kapernaumu lọ lẹhin ijọ melokan; okikí kàn yiká pe, o wà ninu ile.
2Lojukanna ọ̀pọ enia si pejọ tobẹ̃ ti aye kò si fun wọn mọ, kò si, titi de ẹnu-ọ̀na: o si wasu ọ̀rọ na fun wọn.
3Nwọn si wá sọdọ rẹ̀, nwọn gbé ẹnikan ti o li ẹ̀gba tọ̀ ọ wá, ẹniti mẹrin gbé.
4Nigbati nwọn kò si le sunmọ ọ nitori ọ̀pọ enia, nwọn si ṣí orule ile nibiti o gbé wà: nigbati nwọn si da a lu tan, nwọn sọ akete na kalẹ lori eyiti ẹlẹgba na dubulẹ.
5Nigbati Jesu ri igbagbọ́ wọn, o wi fun ẹlẹgba na pe, Ọmọ, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ.
6Ṣugbọn awọn kan ninu awọn akọwe wà ti nwọn joko nibẹ̀, nwọn si ngbèro li ọkàn wọn, wipe,
7Ẽṣe ti ọkunrin yi fi sọrọ bayi? o nsọ ọrọ-odi; tali o le dari eṣẹ jìni bikoṣe ẹnikan, aní Ọlọrun?
8Lojukanna bi Jesu ti woye li ọkàn rẹ̀ pe, nwọn ngbèro bẹ̃ ninu ara wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nrò nkan wọnyi ninu ọkàn nyin?
9 Ewo li o ya jù lati wi fun ẹlẹgba na pe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide, si gbé akete rẹ, ki o si ma rìn?
10 Ṣugbọn ki ẹ le mọ̀ pe, Ọmọ-enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o wi fun ẹlẹgba na pe,)
11 Mo wi fun ọ, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã lọ ile rẹ.
12O si dide lojukanna, o si gbé akete na, o si jade lọ li oju gbogbo wọn; tobẹ̃ ti ẹnu fi yà gbogbo wọn, nwọn si yìn Ọlọrun logo, wipe, Awa ko ri irú eyi rí.
Jesu Pe Lefi
(Mat 9:9-13; Luk 5:27-32)
13O si tún jade lọ si eti okun; gbogbo ijọ enia si wá sọdọ rẹ̀, o si kọ́ wọn.
14Bi o si ti nkọja lọ, o ri Lefi ọmọ Alfeu, o joko ni bode, o si wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. Ó si dide, o tọ̀ ọ lẹhin.
15O si ṣe, bi o si ti joko tì onjẹ ni ile rẹ̀, ọ̀pọ awọn agbowode ati ẹlẹṣẹ wá bá Jesu joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: nitoriti nwọn pọ̀ nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.
16Nigbati awọn akọwe ati awọn Farisi si ri i ti o mbá awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹun, nwọn wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẽtiri ti o fi mba awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹ, ti o si mba wọn mu?
17Nigbati Jesu gbọ́, o wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn le kì iwá oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn ko da: Emi ko wá lati pè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.
Ìbéèrè Nípa Ààwẹ̀ Gbígbà
(Mat 9:14-17; Luk 5:33-39)
18Awọn ọmọ-ẹhin Johanu, ati awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi a ma gbàwẹ: nwọn si wá, nwọn si bi i pe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin Johanu, ati awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi fi ngbàwẹ, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko gbàwẹ?
19Jesu si wi fun wọn pe, Ẹnyin le mu ki awọn ọmọ ile iyawo gbàwe, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn? niwọn igbati nwọn ni ọkọ iyawo lọdọ wọn, nwọn kò le gbàwẹ.
20 Ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn o gbàwẹ ni ijọ wọnni.
21 Ko si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun mọ ogbologbo ẹ̀wu; bi bẹ̃ko eyi titun ti a fi lẹ ẹ a fà ogbologbo ya, aṣọ a si ma ya siwaju.
22 Ko si ẹniti ifi ọti-waini titun sinu ogbologbo ìgo; bi bẹ̃kọ ọti-waini titun a bẹ́ ìgo na, ọti-waini a si danu, ìgo na a si fàya; ṣugbọn ọti-waini titun ni ã fi sinu ìgo titun.
Ìbéèrè Nípa Ọjọ́ Ìsinmi
(Mat 12:1-8; Luk 6:1-5)
23O si ṣe, bi Jesu ti nkọja lọ lãrin oko ọkà li ọjọ isimi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà bi nwọn ti nlọ.
24Awọn Farisi si wi fun u pe, Wo o, ẽṣe ti nwọn fi nṣe eyi ti kò yẹ li ọjọ isimi?
25O si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ti kà ohun ti Dafidi ṣe, nigbati o ṣe alaini, ti ebi si npa a, on, ati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀?
26 Bi o ti wọ̀ inu ile Ọlọrun lọ li ọjọ Abiatari olori alufa, ti o si jẹ akara ifihàn, ti ko tọ́ fun u lati jẹ bikoṣe fun awọn alufa, o si fifun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pẹlu?
27O si wi fun wọn pe, A dá ọjọ isimi nitori enia, a kò dá enia nitori ọjọ isimi:
28 Nitorina Ọmọ-enia li oluwa ọjọ isimi pẹlu.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Mak 2: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.