Num 29

29
Ẹbọ Àjọ̀dún Ọdún Titun
(Lef 23:23-25)
1ATI li oṣù keje, li ọjọ́ kini oṣù na ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: ọjọ́ ifunpe ni fun nyin.
2Ki ẹnyin ki o si fi ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabùku ru ẹbọ sisun fun õrùn didùn si OLUWA:
3Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo kan,
4Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mejeje:
5Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, lati ṣètutu fun nyin;
6Pẹlu ẹbọ sisun oṣù, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn, gẹgẹ bi ìlana wọn, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
Ẹbọ Ọjọ́ Ètùtù
(Lef 23:26-32)
7Ki ẹnyin ki o si ní apejọ mimọ́ ni ijọ́ kẹwa oṣù keje na yi; ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan:
8Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun si OLUWA fun õrùn didùn; ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan; ki nwọn ki o si jẹ́ alailabùku fun nyin:
9Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji ọsuwọn fun àgbo kan,
10Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mejeje:
11Obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ètutu, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn.
12Ati ni ijọ́ kẹdogun oṣù keje, ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan, ki ẹnyin ki o si ṣe ajọ fun OLUWA ni ijọ́ meje:
13Ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ sisun kan, ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu mẹtala, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan; ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku:
14Ati ẹbọ ohun-jijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, bẹ̃ni fun akọmalu mẹtẹtala, idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo kan, bẹ̃ni fun àgbo mejeji,
15Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mẹrẹrinla:
16Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
17Ati ni ijọ́ keji ni ki ẹnyin ki o fi ẹgbọrọ akọmalu mejila, àgbo meji, ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku rubọ:
18Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:
19Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn.
20Ati ni ijọ́ kẹta akọmalu mọkanla, àgbo meji, akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku;
21Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:
22Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
23Ati ni ijọ́ kẹrin akọmalu mẹwa, àgbo meji, ati ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku:
24Ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:
25Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
26Ati ni ijọ́ karun akọmalu mẹsan, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku:
27Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:
28Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
29Ati ni ijọ́ kẹfa akọmalu mẹjọ, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku:
30Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:
31Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
32Ati ni ijọ́ keje akọmalu meje, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku:
33Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:
34Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
35Ni ijọ́ kẹjọ ki ẹnyin ki o ní ajọ ti o ni ironu: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan.
36Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun, ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA: akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabùku:
37Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:
38Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
39Ẹbọ wọnyi ni ki ẹnyin ki o ru si OLUWA li ajọ nyin, pẹlu ẹjẹ́ nyin, ati ẹbọ ọrẹ-atinuwa nyin, fun ẹbọ sisun nyin, ati fun ẹbọ ohunjijẹ nyin, ati fun ẹbọ ohun mimu nyin, ati fun ẹbọ alafia nyin.
40Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ fun Mose.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Num 29: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀