Filp Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìjọ kinni tí Paulu dá sílẹ̀ ní Yuropu (Europe) ni ó kọ ìwé tí ó kọ sí àwọn ará Filipi sí. Filipi jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Masedonia, lábẹ́ ìjọba Romu. Ninu ẹ̀wọ̀n ni Paulu wà tí ó fi kọ ìwé yìí. Àkókò tí ó kọ ọ́ jẹ́ àkókò tí ọkàn rẹ̀ dààmú nítorí àwọn òṣìṣẹ́ onigbagbọ bíi rẹ̀ mìíràn, tí wọ́n lòdì sí i, tí wọ́n sì takò ó. Ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ tí wọn ń kọ́ eniyan ninu ìjọ Filipi ba Paulu lọ́kàn jẹ́. Ṣugbọn sibẹ, ọ̀rọ̀ ayọ̀ tí ó gba gbogbo inú ìwé náà fi hàn pé igbagbọ Paulu jinlẹ̀ ninu Jesu Kristi.
Ìdí tí Paulu fi kọ ìwé rẹ̀ yìí ni láti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn onigbagbọ tí wọ́n wà ní Filipi nítorí ẹ̀bùn tí wọ́n fi ranṣẹ sí i ní àkókò tí ó ṣe aláìní. Ó lo anfaani kíkọ ìwé yìí láti dá wọn lọ́kàn le, kí wọ́n lè ní ìgboyà ati ìbàlẹ̀-ọkàn, láì gbé gbogbo ìyọnu tí òun ní ati èyí tí àwọn náà ní lé ọkàn. Ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Jesu, dípò pé kí wọ́n jẹ́ kí ìwà ìgbéraga ati ti ìmọ-tara-ẹni-nìkan jẹ wọ́n lógún. Ó rán wọn létí pé ẹ̀bùn Ọlọrun ni ìgbé-ayé ìṣọ̀kan ninu Kristi tí wọ́n ní nípa igbagbọ, tí kì í sì í ṣe nípa títẹ̀lé Òfin àwọn Juu. Ó tún kọ nípa ayọ̀ ati alaafia tí Ọlọrun máa ń fún àwọn tí wọn ń gbé ìgbé-ayé ìṣọ̀kan pẹlu Kristi.
Àwọn àmì bíi mélòó kan hàn jákèjádò ìwé yìí, tí ó gbọdọ̀ máa hàn ninu ìgbé-ayé ati ẹ̀sìn onigbagbọ, àwọn ni: àmì ayọ̀, ìbàlẹ̀-ọkàn, ìṣọ̀kan ati ìforítì. Ó tún fi ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ tí Paulu ní sí ìjọ Filipi hàn.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-11
Àwọn nǹǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ sí Paulu 1:12-26
Ìgbé-ayé ninu Kristi 1:27—2:18
Ètò Paulu fún Timoti ati Epafiroditu 2:19-30
Ìkìlọ̀ nípa àwọn ọ̀tá ati ewu 3:1—4:9
Paulu ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní Filipi 4:10-20
Ọ̀rọ̀ ìparí 4:21-23
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Filp Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.