Owe 18
18
1ẸNITI o yà ara rẹ̀ sọtọ̀ yio lepa ifẹ ara rẹ̀, yio si kọju ìja nla si ohunkohun ti iṣe ti oye.
2Aṣiwère kò ni inu-didùn si imoye, ṣugbọn ki o le fi aiya ara rẹ̀ hàn.
3Nigbati enia-buburu ba de, nigbana ni ẹ̀gan de, ati pẹlu ẹ̀gan ni itiju.
4Ọ̀rọ ẹnu enia dabi omi jijìn, orisun ọgbọ́n bi odò ṣiṣàn.
5Kò dara lati ṣe ojuṣãju enia-buburu, lati bì olododo ṣubu ni idajọ.
6Ete aṣiwère bọ sinu ìja, ẹnu rẹ̀ a si ma pè ìna wá.
7Ẹnu aṣiwère ni iparun rẹ̀, ète rẹ̀ si ni ikẹkùn ọkàn rẹ̀.
8Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ.
9Ẹniti o lọra pẹlu ni iṣẹ rẹ̀, arakunrin jẹguduragudu enia ni.
10Orukọ Oluwa, ile-iṣọ agbara ni: Olododo sá wọ inu rẹ̀, o si là.
11Ọrọ̀ ọlọrọ̀ ni ilu-agbara rẹ̀, o si dabi odi giga li oju ara rẹ̀.
12Ṣaju iparun, aiya enia a ṣe agidi, ṣaju ọlá si ni irẹlẹ.
13Ẹniti o ba dahùn ọ̀rọ ki o to gbọ́, wère ati itiju ni fun u.
14Ọkàn enia yio faiyàrán ailera rẹ̀; ṣugbọn ọkàn ti o rẹ̀wẹsi, tani yio gbà a?
15Aiya amoye ni ìmọ; eti ọlọgbọ́n a si ma ṣe afẹri ìmọ.
16Ọrẹ enia a ma fi àye fun u, a si mu u wá siwaju awọn enia nla.
17Ẹnikini ninu ẹjọ rẹ̀ a dabi ẹnipe o jare, ṣugbọn ẹnikeji rẹ̀ a wá, a si hudi rẹ̀ silẹ.
18Keké mu ìja pari, a si làja lãrin awọn alagbara.
19Arakunrin ti a ṣẹ̀ si, o ṣoro jù ilu olodi lọ: ìja wọn si dabi ọpá idabu ãfin.
20Ọ̀rọ ẹnu enia ni yio mu inu rẹ̀ tutu: ibisi ẹnu rẹ̀ li a o si fi tù u ninu.
21Ikú ati ìye mbẹ ni ipa ahọn: awọn ẹniti o ba si nlò o yio jẹ ère rẹ̀.
22Ẹnikẹni ti o ri aya fẹ, o ri ohun rere, o si ri ojurere lọdọ Oluwa.
23Talaka a ma bẹ̀ ẹ̀bẹ; ṣugbọn ọlọrọ̀ a ma fi ikanra dahùn.
24Ẹniti o ni ọrẹ́ pupọ, o ṣe e si iparun ara rẹ̀; ọrẹ́ kan si mbẹ ti o fi ara mọni ju arakunrin lọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Owe 18: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.