Owe 21
21
1AIYA ọba mbẹ lọwọ Oluwa bi odò omi; on a si dari rẹ̀ si ìbikibi ti o wù u.
2Gbogbo ọ̀na enia li o dara li oju ara rẹ̀: ṣugbọn Oluwa li o nṣe amọ̀na ọkàn.
3Lati ṣe ododo ati idajọ, o ṣe itẹwọgba fun Oluwa jù ẹbọ lọ.
4Gangan oju, ati igberaga aiya, ati itulẹ̀ enia buburu, ẹ̀ṣẹ ni.
5Ìronu alãpọn si kiki ọ̀pọ ni; ṣugbọn ti olukuluku ẹniti o yara, si kiki aini ni.
6Ini iṣura nipa ahọn eke, o jẹ ẽmi ti a ntì sihin tì sọhun lọwọ awọn ti nwá ikú kiri.
7Iwa-agbara awọn enia buburu ni yio pa wọn run: nitori ti nwọn kọ̀ lati ṣe idajọ.
8Ẹnikẹni ti o nrìn ọ̀na ayidayida, enia buburu ni; ṣugbọn oninu funfun ni iṣẹ rẹ̀ tọ́.
9O san lati joko ni igun òke àja, jù pẹlu onija obinrin lọ ninu ile ajumọgbe.
10Ọkàn enia buburu nwá ibi kiri: aladugbo rẹ̀ kò ri ojurere li oju rẹ̀.
11Nigbati a ba jẹ ẹlẹgàn ni ìya, a sọ òpe di ọlọgbọ́n: nigbati a ba si nkọ́ ọlọgbọ́n, on o ma ni ìmọ.
12Olododo kiyesi ile enia buburu: pe ẹnikan wà ti yio bì enia buburu ṣubu sinu iparun.
13Ẹnikẹni ti o ba di eti rẹ̀ si igbe olupọnju, ontikararẹ̀ yio ke pẹlu: ṣugbọn a kì yio gbọ́.
14Ọrẹ ikọkọ, o tù ibinu: ati ẹ̀bun ni iṣẹpo-aṣọ, o tù ibinu lile.
15Ayọ̀ ni fun olododo lati ṣe idajọ: ṣugbọn iparun ni fun awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.
16Ẹniti o ba yà kuro li ọ̀na oye, yio ma gbe inu ijọ awọn okú.
17Ẹniti o ba fẹ afẹ, yio di talaka: ẹniti o fẹ ọti-waini pẹlu ororo kò le lọrọ̀.
18Enia buburu ni yio ṣe owo-irapada fun olododo, ati olurekọja ni ipò ẹni diduro-ṣinṣin.
19O san lati joko li aginju jù pẹlu onija obinrin ati oṣónu lọ.
20Iṣura fifẹ ati ororo wà ni ibugbe ọlọgbọ́n; ṣugbọn enia aṣiwère ná a bajẹ.
21Ẹniti o ba tẹle ododo ati ãnu, a ri ìye, ododo, ati ọlá.
22Ọlọgbọ́n gùn odi ilu awọn alagbara, a si fi idi agbara igbẹkẹle rẹ̀ jalẹ̀.
23Ẹnikẹni ti o ba pa ẹnu ati ahọn rẹ̀ mọ́, o pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kuro ninu iyọnu.
24Agberaga ati agidi ẹlẹgàn li orukọ rẹ̀, ẹniti nhùwa ninu ibinu pupọpupọ.
25Ifẹ ọlẹ pa a; nitoriti, ọwọ rẹ̀ kọ̀ iṣẹ ṣiṣe.
26O nfi ilara ṣojukokoro ni gbogbo ọjọ: ṣugbọn olododo a ma fi funni kì si idawọduro.
27Ẹbọ enia buburu, irira ni: melomelo ni nigbati o mu u wá ti on ti ìwakiwa rẹ̀?
28Ẹlẹri eke yio ṣegbe: ṣugbọn ẹniti o gbọ́, yio ma sọ̀rọ li aiyannu.
29Enia buburu gbè oju rẹ̀ le: ṣugbọn ẹni iduro-ṣinṣin li o nmu ọ̀na rẹ̀ tọ̀.
30Kò si ọgbọ́n, kò si imoye, tabi ìgbimọ si Oluwa.
31A mura ẹṣin silẹ de ọjọ ogun: ṣugbọn iṣẹgun lati ọwọ Oluwa ni.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Owe 21: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.