O. Daf 111
111
Yin OLUWA
1Ẹ ma yìn Oluwa. Emi o ma yìn Oluwa tinutinu mi, ninu ijọ awọn ẹni diduro-ṣinṣin, ati ni ijọ enia.
2Iṣẹ Oluwa tobi, iwa-kiri ni fun gbogbo awọn ti o ni ifẹ rẹ̀ ninu.
3Iṣe rẹ̀ li ọlá on ogo, ododo rẹ̀ si duro lailai.
4O ṣe iṣẹ iyanu rẹ̀ ni iranti: olore-ọfẹ́ li Oluwa o si kún fun ãnu.
5O ti fi onjẹ fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀: yio ranti majẹmu rẹ̀ lailai.
6O ti fi iṣẹ agbara rẹ̀ hàn awọn enia rẹ̀, ki o le fun wọn ni ilẹ-ini awọn keferi.
7Otitọ ati idajọ ni iṣẹ ọwọ rẹ̀; gbogbo ofin rẹ̀ li o daniloju.
8Nwọn duro lai ati lailai, ninu otitọ ati iduro-ṣinṣin li a ṣe wọn.
9O rán idande si awọn enia rẹ̀: o ti paṣẹ majẹmu rẹ̀ lailai: mimọ́ ati ọ̀wọ li orukọ rẹ̀.
10Ibẹru Oluwa ni ipilẹṣẹ ọgbọ́n: oye rere ni gbogbo awọn ti npa ofin rẹ̀ mọ́ ni: iyìn rẹ̀ duro lailai.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 111: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.