O. Daf 140
140
Adura Ààbò
1OLUWA gbà mi lọwọ ọkunrin buburu nì, yọ mi lọwọ ọkunrin ìka nì;
2Ẹniti nrò ìwa-buburu ni inu wọn; nigbagbogbo ni nwọn nrú ìja soke si mi.
3Nwọn ti pọ́n ahọn wọn bi ejo; oro pãmọlẹ mbẹ li abẹ ète wọn.
4Oluwa, pa mi mọ́ kuro lọwọ enia buburu; yọ mi kuro lọwọ ọkunrin ìka nì; ẹniti o ti pinnu rẹ̀ lati bì ìrin mi ṣubu.
5Awọn agberaga dẹ pakute silẹ fun mi, ati okùn; nwọn ti nà àwọn lẹba ọ̀na; nwọn ti kẹkùn silẹ fun mi.
6Emi wi fun Oluwa pe, iwọ li Ọlọrun mi: Oluwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi.
7Ọlọrun Oluwa, agbara igbala mi, iwọ li o bò ori mi mọlẹ li ọjọ ìja.
8Oluwa, máṣe fi ifẹ enia buburu fun u: máṣe kún ọgbọ́n buburu rẹ̀ lọwọ: ki nwọn ki o má ba gbé ara wọn ga.
9Bi o ṣe ti ori awọn ti o yi mi ká kiri ni, jẹ ki ìka ète ara wọn ki o bò wọn mọlẹ.
10A o da ẹyin iná si wọn lara: on o wọ́ wọn lọ sinu iná, sinu ọgbun omi jijin, ki nwọn ki o má le dide mọ́.
11Máṣe jẹ ki alahọn buburu ki o fi ẹsẹ mulẹ li aiye: ibi ni yio ma dọdẹ ọkunrin ìka nì lati bì i ṣubu.
12Emi mọ̀ pe, Oluwa yio mu ọ̀ran olupọnju duro, ati are awọn talaka.
13Nitõtọ awọn olododo yio ma fi ọpẹ fun orukọ rẹ: awọn ẹni diduro-ṣinṣin yio ma gbe iwaju rẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 140: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.