O. Daf 145

145
Orin Ìyìn
1EMI o gbé ọ ga, Ọlọrun mi, ọba mi; emi o si ma fi ibukún fun orukọ rẹ lai ati lailai.
2Li ojojumọ li emi o ma fi ibukún fun ọ; emi o si ma yìn orukọ rẹ lai ati lailai.
3Titobi li Oluwa, o si ni iyìn pupọ̀-pupọ̀; awamaridi si ni titobi rẹ̀.
4Iran kan yio ma yìn iṣẹ rẹ de ekeji, yio si ma sọ̀rọ iṣẹ agbara rẹ.
5Emi o sọ̀rọ iyìn ọla-nla rẹ ti o logo, ati ti iṣẹ iyanu rẹ.
6Enia o si ma sọ̀rọ agbara iṣẹ rẹ ti o li ẹ̀ru; emi o si ma ròhin titobi rẹ.
7Nwọn o ma sọ̀rọ iranti ore rẹ pupọ̀-pupọ̀, nwọn o si ma kọrin ododo rẹ.
8Olore-ọfẹ li Oluwa, o kún fun ãnu; o lọra lati binu, o si li ãnu pupọ̀.
9Oluwa ṣeun fun ẹni gbogbo; iyọ́nu rẹ̀ si mbẹ lori iṣẹ rẹ̀ gbogbo.
10Oluwa, gbogbo iṣẹ rẹ ni yio ma yìn ọ; awọn enia mimọ́ rẹ yio si ma fi ibukún fun ọ.
11Nwọn o ma sọ̀rọ ogo ijọba rẹ, nwọn o si ma sọ̀rọ agbara rẹ:
12Lati mu iṣẹ agbara rẹ̀ di mimọ̀ fun awọn ọmọ enia, ati ọla-nla ijọba rẹ̀ ti o logo,
13Ijọba rẹ ijọba aiye-raiye ni, ati ijọba rẹ lati iran-diran gbogbo.
14Oluwa mu gbogbo awọn ti o ṣubu ró; o si gbé gbogbo awọn ti o tẹriba dide.
15Oju gbogbo enia nwò ọ; iwọ si fun wọn li onjẹ wọn li akokò rẹ̀.
16Iwọ ṣi ọwọ rẹ, iwọ si tẹ́ ifẹ gbogbo ohun alãye lọrùn.
17Olododo li Oluwa li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, ati alãnu ni iṣẹ rẹ̀ gbogbo.
18Oluwa wà leti ọdọ gbogbo awọn ti nkepè e, leti ọdọ gbogbo ẹniti nkepè e li otitọ.
19Yio mu ifẹ awọn ti mbẹ̀ru rẹ̀ ṣẹ: yio gbọ́ igbe wọn pẹlu, yio si gbà wọn.
20Oluwa da gbogbo awọn ti o fẹ ẹ si: ṣugbọn gbogbo enia buburu ni yio parun.
21Ẹnu mi yio ma sọ̀rọ iyìn Oluwa: ki gbogbo enia ki o si ma fi ibukún fun orukọ rẹ̀ mimọ́ lai ati lailai.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 145: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀