O. Daf 18

18
Orin Ìṣẹ́gun
Orin Dafidi, iranṣẹ Oluwa, ẹniti o sọ ọ̀rọ orin yi fun Oluwa li ọjọ ti Oluwa gbà a kuro lọwọ gbogbo awọn ọta rẹ̀, ati lọwọ Saulu.
1EMI o fẹ ọ, Oluwa, agbara mi.
2Oluwa li apáta mi, ati ilu-olodi mi, ati olugbala mi: Ọlọrun mi, agbara mi, emi o gbẹkẹle e; asà mi, ati iwo igbala mi, ati ile-iṣọ giga mi.
3Emi o kepè Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn; bẹ̃li a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi.
4Irora ikú yi mi ka, ati iṣàn-omi awọn enia buburu dẹ̀ruba mi.
5Irora ipò okú yi mi kakiri: ikẹkun ikú dì mi mu.
6Ninu ìṣẹ́ mi emi kepè Oluwa, emi si sọkun pe Ọlọrun mi: o gbohùn mi lati inu tempili rẹ̀ wá, ẹkún mi si wá si iwaju rẹ̀, ani si eti rẹ̀.
7Nigbana ni ilẹ mì, o si wariri: ipilẹ òke pẹlu ṣidi, o si mì, nitoriti o binu.
8Ẹ̃fin ti iho imu rẹ̀ jade, ati iná lati ẹnu rẹ̀ wá njonirun: ẹyín gbiná nipasẹ rẹ̀.
9O tẹri ọrun ba pẹlu, o si sọkalẹ wá: òkunkun si mbẹ li abẹ ẹsẹ rẹ̀.
10O si gùn ori kerubu o si fò: nitõtọ, o nra lori iyẹ-apa afẹ́fẹ́.
11O fi òkunkun ṣe ibi ìkọkọ rẹ̀: ani agọ́ rẹ̀ yi i ka kiri; omi dudu, ati awọsanma oju-ọrun ṣiṣu dudu.
12Nipa imọlẹ iwaju rẹ̀, awọsanma ṣiṣu dùdu rẹ̀ kọja lọ, yinyín ati ẹyín iná.
13Oluwa sán ãra pẹlu li ọrun, Ọga-ogo si fọ̀ ohùn rẹ̀: yinyín ati ẹyín iná!
14Lõtọ, o rán ọfa rẹ̀ jade, o si tú wọn ká: ọ̀pọlọpọ manamana li o si fi ṣẹ́ wọn tũtu.
15Nigbana li awowò omi odò hàn, a si ri ipilẹ aiye nipa ibawi rẹ, Oluwa, nipa fifun ẽmi iho imu rẹ.
16O ranṣẹ́ lati òke wá, o mu mi, o fà mi jade wá lati inu omi nla.
17O gbà mi lọwọ ọta mi alagbara, ati lọwọ awọn ti o korira mi; nitori nwọn li agbara jù mi lọ.
18Nwọn dojukọ mi li ọjọ ipọnju mi: ṣugbọn Oluwa li alafẹhintì mi.
19O mu mi jade pẹlu sinu ibi nla; o gbà mi nitori inu rẹ̀ dùn si mi.
20Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi; gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ mi li o san a fun mi.
21Nitori mo ti nkiye si ọ̀na Oluwa, emi kò fi ìka yà kuro lọdọ Ọlọrun mi.
22Nitori pe gbogbo idajọ rẹ̀ li o wà niwaju mi, bẹ̃li emi kò si yẹ̀ ofin rẹ̀ kuro lọdọ mi.
23Emi si duro ṣinṣin pẹlu rẹ̀, emi si paramọ kuro lara ẹ̀ṣẹ mi.
24Nitorina li Oluwa ṣe san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi, gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ mi li oju rẹ̀.
25Fun alãnu ni iwọ o fi ara rẹ hàn li alãnu; fun ẹniti o duro-ṣinṣin ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni diduro-ṣinṣin.
26Fun ọlọkàn-mimọ́ ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni ọlọkàn-mimọ́; ati fun ọlọkàn-wiwọ ni iwọ o fi ara rẹ hàn li onroro.
27Nitori iwọ o gbà awọn olupọnju; ṣugbọn iwọ o sọ oju igberaga kalẹ.
28Nitori iwọ ni yio tàn fitila mi: Oluwa Ọlọrun mi yio tàn imọlẹ si òkunkun mi.
29Nitori pe pẹlu rẹ emi sure là inu ogun lọ: ati pẹlu Ọlọrun mi emi fò odi kan.
30Bi o ṣe ti Ọlọrun ni, ọ̀na rẹ̀ pé: a ti ridi ọ̀rọ Oluwa: on li apata fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e.
31Nitori pe tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe Oluwa? tabi tani iṣe apáta bikoṣe Ọlọrun wa?
32Ọlọrun li o fi agbara dì mi li amure, o si mu ọ̀na mi pé.
33O ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ àgbọnrín, o si gbé mi kà ibi giga mi.
34O kọ́ ọwọ mi li ogun jija, tobẹ̃ ti apa mi fà ọrun idẹ.
35Iwọ ti fi asà igbala rẹ fun mi pẹlu: ọwọ ọ̀tun rẹ si gbé mi duro, ati ìwa-pẹlẹ rẹ sọ mi di nla.
36Iwọ sọ ìrin ẹsẹ mi di nla nisalẹ mi, ki kóko-ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀.
37Emi ti le awọn ọta mi, emi si bá wọn: bẹ̃li emi kò pada sẹhin titi a fi run wọn.
38Emi ṣá wọn li ọgbẹ ti nwọn kò fi le dide, nwọn ṣubu li abẹ ẹsẹ mi.
39Nitoriti iwọ fi agbara di mi li àmure si ogun na: iwọ ti mu awọn ti o dide si mi tẹriba li abẹ ẹsẹ mi.
40Iwọ si yi ẹhin awọn ọta mi pada fun mi pẹlu; emi si pa awọn ti o korira mi run.
41Nwọn kigbe, ṣugbọn kò si ẹniti o gbà wọn; ani si Oluwa, ṣugbọn kò dá wọn li ohùn.
42Nigbana ni mo gún wọn kunna bi ekuru niwaju afẹfẹ: mo kó wọn jade bi ohun ẹ̀gbin ni ita.
43Iwọ ti yọ mi kuro ninu ìja awọn enia; iwọ fi mi jẹ olori awọn orilẹ-ède: enia ti emi kò ti mọ̀, yio si ma sìn mi.
44Bi nwọn ti gburo mi, nwọn o gbà mi gbọ́: awọn ọmọ àjeji yio fi ẹ̀tan tẹ̀ ori wọn ba fun mi.
45Aiya yio pá awọn alejo, nwọn o si fi ibẹ̀ru jade ni ibi kọlọfin wọn.
46Oluwa mbẹ; olubukún si li apáta mi; ki a si gbé Ọlọrun igbala mi leke.
47Ọlọrun li o ngbẹsan mi, ti o si nṣẹ́ awọn enia fun mi.
48O gbà mi lọwọ awọn ọta mi: pẹlupẹlu iwọ gbé mi leke jù awọn ti o dide si mi lọ; iwọ ti gbà mi lọwọ ọkunrin alagbara nì.
49Nitorina li emi ṣe fi iyìn fun ọ, Oluwa, li awujọ awọn orilẹ-ède, emi o si ma kọrin iyìn si orukọ rẹ.
50Ẹniti o fi igbala nla fun Ọba rẹ̀; o si fi ãnu hàn fun Ẹni-ororo rẹ̀, fun Dafidi, ati fun iru-ọmọ rẹ̀ lailai.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 18: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀