O. Daf 22

22
Igbe Ìrora ati Orin Ìyìn
1ỌLỌRUN mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ? ti iwọ si jina si igbala mi, ati si ohùn igbe mi?
2Ọlọrun mi, emi nkigbe li ọsan, ṣugbọn iwọ kò dahùn: ati ni igba oru emi kò dakẹ.
3Ṣugbọn mimọ́ ni Iwọ, ẹniti o tẹ̀ iyìn Israeli do.
4Awọn baba wa gbẹkẹle ọ: nwọn gbẹkẹle, iwọ si gbà wọn.
5Nwọn kigbe pè ọ, a si gbà wọn: nwọn gbẹkẹle ọ, nwọn kò si dãmu.
6Ṣugbọn kòkoro li emi, kì isi iṣe enia; ẹ̀gan awọn enia, ati ẹlẹya awọn enia.
7Gbogbo awọn ti o ri mi nfi mi rẹrin ẹlẹya: nwọn nyọ ṣuti ète wọn, nwọn nmì ori pe,
8Jẹ́ ki o gbẹkẹle Oluwa, on o gbà a là; jẹ ki o gbà a là nitori inu rẹ̀ dùn si i.
9Ṣugbọn iwọ li ẹniti o mu mi jade lati inu wá: iwọ li o mu mi wà li ailewu, nigbati mo rọ̀ mọ́ ọmu iya mi.
10Iwọ li a ti fi mi le lọwọ lati inu iya mi wá: iwọ li Ọlọrun mi lati inu iya mi wá.
11Máṣe jina si mi; nitori ti iyọnu sunmọ etile; nitoriti kò si oluranlọwọ.
12Akọ-malu pipọ̀ li o yi mi ka: malu Baṣani ti o lagbara rọ̀gba yi mi ka.
13Nwọn yà ẹnu wọn si mi, bi kiniun ti ndọdẹ kiri, ti nké ramuramu.
14A tú mi danu bi omi, gbogbo egungun mi si yẹ̀ lori ike: ọkàn mi dabi ida; o yọ́ larin inu mi.
15Agbara mi di gbigbẹ bi apãdi: ahọn mi si lẹ̀ mọ́ mi li ẹrẹkẹ; iwọ o mu mi dubulẹ ninu erupẹ ikú.
16Nitoriti awọn aja yi mi ka: ijọ awọn enia buburu ti ká mi mọ́: nwọn lu mi li ọwọ, nwọn si lu mi li ẹsẹ.
17Mo le kaye gbogbo egungun mi: nwọn tẹjumọ mi; nwọn nwò mi sùn.
18Nwọn pín aṣọ mi fun ara wọn, nwọn si ṣẹ́ keké le aṣọ-ileke mi.
19Ṣugbọn iwọ máṣe jina si mi, Oluwa: agbara mi, yara lati ràn mi lọwọ.
20Gbà ọkàn mi lọwọ idà; ẹni mi kanna lọwọ agbara aja nì.
21Gbà mi kuro li ẹnu kiniun nì; ki iwọ ki o si gbohùn mi lati ibi iwo awọn agbanrere.
22Emi o sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn arakunrin mi: li awujọ ijọ li emi o ma yìn ọ,
23Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ yìn i; gbogbo ẹnyin iru-ọmọ Jakobu, ẹ yìn i logo: ki ẹ si ma bẹ̀ru rẹ̀ gidigidi, gbogbo ẹnyin irú-ọmọ Israeli.
24Nitoriti kò kẹgan, bẹ̃ni kò korira ipọnju awọn olupọnju; bẹ̃ni kò pa oju rẹ̀ mọ́ kuro lara rẹ̀; ṣugbọn nigbati o kigbe pè e, o gbọ́.
25Nipa tirẹ ni iyìn mi yio wà ninu ajọ nla, emi o san ẹjẹ́ mi niwaju awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀.
26Awọn olupọnju yio jẹ, yio tẹ́ wọn lọrun: awọn ti nwá Oluwa yio yìn i: ọkàn nyin yio wà lailai:
27Gbogbo opin aiye ni yio ranti, nwọn o si yipada si Oluwa: ati gbogbo ibatan orilẹ-ède ni yio wolẹ-sìn niwaju rẹ̀.
28Nitori ijọba ni ti Oluwa; on si ni Bãlẹ ninu awọn orilẹ-ède.
29Gbogbo awọn ti o sanra li aiye yio ma jẹ, nwọn o si ma wolẹ-sìn: gbogbo awọn ti nsọkalẹ lọ sinu erupẹ yio tẹriba niwaju rẹ̀, ati ẹniti kò le pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ li ãye.
30Iru kan yio ma sìn i; a o si kà a ni iran kan fun Oluwa.
31Nwọn o wá, nwọn o si ma sọ̀rọ ododo rẹ̀ fun awọn enia kan ti a o bí, pe, on li o ṣe eyi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 22: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀