O. Daf 24

24
Ọba Atóbijù
1TI Oluwa ni ilẹ, ati ẹkún rẹ̀; aiye, ati awọn ti o tẹdo sinu rẹ̀.
2Nitoriti o fi idi rẹ̀ sọlẹ lori okun, o si gbé e kalẹ lori awọn iṣan-omi.
3Tani yio gùn ori oke Oluwa lọ? tabi tani yio duro ni ibi-mimọ́ rẹ̀?
4Ẹniti o li ọwọ mimọ́, ati aiya funfun: ẹniti kò gbé ọkàn rẹ̀ soke si asan, ti kò si bura ẹ̀tan.
5On ni yio ri ibukún gbà lọwọ Oluwa, ati ododo lọwọ Ọlọrun igbala rẹ̀.
6Eyi ni iran awọn ti nṣe afẹri rẹ̀, ti nṣe afẹri rẹ, Ọlọrun Jakobu.
7Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọ̀na; ki a si gbé nyin soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ̀ inu ile wa.
8Tali Ọba ogo yi? Oluwa ti o le, ti o si lagbara, Oluwa ti o lagbara li ogun.
9Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọ̀na; ani ki ẹ gbé wọn soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ̀ inu ile wa.
10Tali Ọba ogo yi? Oluwa awọn ọmọ-ogun; on na li Ọba ogo.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 24: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀