O. Daf 28
28
Adura Ìrànlọ́wọ́
1IWỌ, Oluwa, apata mi li emi o kigbe pè, máṣe dakẹ si mi; bi iwọ ba dakẹ si mi, emi o dabi awọn ti o lọ sinu ihò.
2Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi, nigbati mo ba nkigbe pè ọ, nigbati mo ba gbé ọwọ mi soke siha ibi-mimọ́ jùlọ rẹ.
3Máṣe fà mi lọ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ, ti nsọ̀rọ alafia si aladugbo wọn, ṣugbọn ìwa-ìka mbẹ̀ li ọkàn wọn.
4Fi fun wọn gẹgẹ bi iṣe wọn, ati gẹgẹ bi ìwa buburu ete wọn, fi fun wọn nipa iṣẹ ọwọ wọn, fi ère wọn fun wọn.
5Nitori ti nwọn kò kà iṣẹ Oluwa si, tabi iṣẹ ọwọ rẹ̀; on o run wọn, kì yio si gbé wọn ró.
6Olubukún ni Oluwa, nitoriti o ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi.
7Oluwa li agbara ati asà mi; on li aiya mi gbẹkẹle, a si nràn mi lọwọ: nitorina inu mi dùn jọjọ: emi o si ma fi orin mi yìn i.
8Oluwa li agbara wọn, on si li agbara igbala ẹni-ororo rẹ̀.
9Gbà awọn enia rẹ là, ki o si busi ilẹ-ini rẹ: ma bọ́ wọn pẹlu, ki o si ma gbé wọn leke lailai.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 28: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.