O. Daf 35
35
Adura ìrànlọ́wọ́
1OLUWA gbogun tì awọn ti o gbogun tì mi: fi ìja fun awọn ti mba mi jà.
2Di asà on apata mu, ki o si dide fun iranlọwọ mi.
3Fa ọ̀kọ yọ pẹlu, ki o si dèna awọn ti nṣe inunibini si mi: wi fun ọkàn mi pe, emi ni igbala rẹ.
4Ki nwọn ki o dãmu, ki a si tì awọn ti nwá ọkàn mi loju: ki a si mu wọn pada, ki a si dãmu awọn ti ngbiro ipalara mi.
5Ki nwọn ki o dabi iyangbo niwaju afẹfẹ: ki angeli Oluwa ki o ma le wọn.
6Ki ọ̀na wọn ki o ṣokunkun ki o si ma yọ́; ki angeli Oluwa ki o si ma lepa wọn.
7Nitori pe, li ainidi ni nwọn dẹ àwọn wọn silẹ fun mi, nwọn wà iho silẹ fun ọkàn mi li ainidi.
8Ki iparun ki o wá si ori rẹ̀ li ojiji; àwọn rẹ̀ ti o dẹ, ki o mu on tikararẹ̀: iparun na ni ki o ṣubu si.
9Ọkàn mi yio si ma yọ̀ niti Oluwa: yio si ma yọ̀ ninu igbala rẹ̀.
10Gbogbo egungun mi ni yio wipe, Oluwa, tali o dabi iwọ, ti ngbà talaka lọwọ awọn ti o lagbara jù u lọ, ani talaka ati alaini lọwọ ẹniti nfi ṣe ikogun?
11Awọn ẹlẹri eke dide; nwọn mbi mi li ohun ti emi kò mọ̀.
12Nwọn fi buburu san ore fun mi, lati sọ ọkàn mi di ofo.
13Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, nigbati ara wọn kò dá, aṣọ àwẹ li aṣọ mi: mo fi àwẹ rẹ̀ ọkàn mi silẹ; adura mi si pada si mi li aiya.
14Emi ṣe ara mi bi ẹnipe ọrẹ tabi arakunrin mi tilẹ ni: emi fi ibinujẹ tẹriba, bi ẹniti nṣọ̀fọ iya rẹ̀.
15Ṣugbọn ninu ipọnju mi nwọn yọ̀, nwọn si kó ara wọn jọ: awọn enia-kenia kó ara wọn jọ si mi, emi kò si mọ̀; nwọn fa mi ya, nwọn kò si dakẹ.
16Pẹlu awọn àgabagebe ti iṣe ẹlẹya li apejẹ, nwọn npa ehin wọn si mi.
17Oluwa iwọ o ti ma wò pẹ to? yọ ọkàn mi kuro ninu iparun wọn, ẹni mi kanna lọwọ awọn kiniun.
18Emi o ṣọpẹ fun ọ ninu ajọ nla: emi o ma yìn ọ li awujọ ọ̀pọ enia.
19Máṣe jẹ ki awọn ti nṣe ọta mi lodi ki o yọ̀ mi; bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ ki awọn ti o korira mi li ainidi ki o ma ṣẹju si mi.
20Nitori ti nwọn kò sọ̀rọ alafia: ṣugbọn nwọn humọ ọ̀ran ẹ̀tan si awọn enia jẹjẹ ilẹ na.
21Nitotọ, nwọn ya ẹnu wọn silẹ si mi, nwọn wipe, A! ã! oju wa ti ri i!
22Eyi ni iwọ ti ri, Oluwa: máṣe dakẹ: Oluwa máṣe jina si mi.
23Rú ara rẹ soke, ki o si ji si idajọ mi, ati si ọ̀ran mi, Ọlọrun mi ati Oluwa mi.
24Ṣe idajọ mi, Oluwa Ọlọrun mi, gẹgẹ bi ododo rẹ, ki o má si ṣe jẹ ki nwọn ki o yọ̀ mi.
25Máṣe jẹ ki nwọn kí o wi ninu ọkàn wọn pe, A! bẹ̃li awa nfẹ ẹ: máṣe jẹ ki nwọn ki o wipe, Awa ti gbé e mì.
26Ki oju ki o tì wọn, ki nwọn ki o si dãmu pọ̀, ti nyọ̀ si ifarapa mi: ki a fi itiju ati àbuku wọ̀ wọn ni aṣọ, ti ngberaga si mi.
27Jẹ ki nwọn ki o ma hó fun ayọ̀, ki nwọn ki o si ma ṣe inu-didùn, ti nṣe oju-rere si ododo mi: lõtọ ki nwọn ki o ma wi titi pe, Oluwa ni ki a ma gbega, ti o ni inu-didùn si alafia iranṣẹ rẹ̀.
28Ahọn mi yio si ma sọ̀rọ ododo rẹ, ati ti iyìn rẹ ni gbogbo ọjọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 35: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.