O. Daf 37

37
Ìgbẹ̀yìn Àwọn Eniyan Burúkú
1MÁṢE ikanra nitori awọn oluṣe-buburu, ki iwọ ki o máṣe ilara nitori awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.
2Nitori ti a o ke wọn lulẹ laipẹ bi koriko, nwọn o si rọ bi eweko tutù.
3Gbẹkẹle Oluwa, ki o si ma ṣe rere; ma gbe ilẹ na, ki o si ma huwa otitọ.
4Ṣe inu-didùn si Oluwa pẹlu, on o si fi ifẹ inu rẹ̀ fun ọ.
5Fi ọ̀na rẹ̀ le Oluwa lọwọ; gbẹkẹle e pẹlu; on o si mu u ṣẹ.
6Yio si mu ododo rẹ jade bi imọlẹ, ati idajọ rẹ bi ọsángangan.
7Iwọ simi ninu Oluwa, ki o si fi sũru duro dè e; máṣe ikanra nitori ẹniti o nri rere li ọ̀na rẹ̀, nitori ọkunrin na ti o nmu èro buburu ṣẹ.
8Dakẹ inu-bibi, ki o si kọ̀ ikannu silẹ: máṣe ikanra, ki o má ba ṣe buburu pẹlu.
9Nitori ti a o ke awọn oluṣe-buburu kuro: ṣugbọn awọn ti o duro de Oluwa ni yio jogun aiye.
10Nitori pe nigba diẹ, awọn enia buburu kì yio si: nitotọ iwọ o fi ara balẹ wò ipò rẹ̀, kì yio si si.
11Ṣugbọn awọn ọlọkàn-tutù ni yio jogun aiye; nwọn o si ma ṣe inu didùn ninu ọ̀pọlọpọ alafia.
12Enia buburu di rikiṣi si olõtọ, o si pa ehin rẹ̀ keke si i lara.
13Oluwa yio rẹrin rẹ̀; nitori ti o ri pe, ọjọ rẹ̀ mbọ̀.
14Awọn enia buburu ti fà idà yọ, nwọn si ti fà ọrun wọn le, lati sọ talaka ati alaini kalẹ, ati lati pa iru awọn ti nrin li ọ̀na titọ.
15Idà wọn yio wọ̀ aiya wọn lọ, ọrun wọn yio si ṣẹ́.
16Ohun diẹ ti olododo ni sanju ọrọ̀ ọ̀pọ enia buburu.
17Nitoriti a o ṣẹ́ apa awọn enia buburu: ṣugbọn Oluwa di olododo mu.
18Oluwa mọ̀ ọjọ ẹni iduro-ṣinṣin: ati ilẹ-ini wọn yio wà lailai.
19Oju kì yio tì wọn ni igba ibi: ati li ọjọ ìyan a o tẹ́ wọn lọrun.
20Ṣugbọn awọn enia buburu yio ṣegbe, awọn ọta Oluwa yio dabi ẹwà oko-tutu: nwọn o run; ẹ̃fin ni nwọn o run si.
21Awọn enia buburu wín, nwọn kò si pada san: ṣugbọn olododo a ma ṣãnu, a si ma fi funni.
22Nitoriti awọn ẹni-ibukún rẹ̀ ni yio jogun aiye; awọn ẹni-egún rẹ̀ li a o ke kuro.
23A ṣe ìlana ẹsẹ enia lati ọwọ Oluwa wá: o si ṣe inu didùn si ọ̀na rẹ̀.
24Bi o tilẹ ṣubu, a kì yio ta a nù kuro patapata; nitoriti Oluwa di ọwọ rẹ̀ mu.
25Emi ti wà li ewe, emi si dagba; emi kò ti iri ki a kọ̀ olododo silẹ, tabi ki iru-ọmọ rẹ̀ ki o ma ṣagbe onjẹ.
26Alãnu li on nigbagbogbo, a ma wín ni: a si ma busi i fun iru-ọmọ rẹ̀.
27Kuro ninu ibi ki o si ma ṣe rere; ki o si ma joko lailai.
28Nitoriti Oluwa fẹ idajọ, kò si kọ̀ awọn enia mimọ́ rẹ̀ silẹ; a si pa wọn mọ́ lailai: ṣugbọn iru-ọmọ awọn enia buburu li a o ke kuro.
29Olododo ni yio jogun aiye, yio si ma gbe inu rẹ̀ lailai.
30Ẹnu olododo ni ima sọ̀rọ ọgbọ́n, ahọn rẹ̀ a si ma sọ̀rọ idajọ.
31Ofin Ọlọrun rẹ̀ mbẹ li aiya rẹ̀; ọkan ninu ìrin rẹ̀ kì yio yẹ̀.
32Ẹni buburu nṣọ olododo, o si nwá ọ̀na lati pa a.
33Oluwa kì yio fi i le e lọwọ, kì yio si da a lẹbi, nigbati a ba nṣe idajọ rẹ̀.
34Duro de Oluwa, ki o si ma pa ọ̀na rẹ̀ mọ́, yio si gbé ọ leke lati jogun aiye: nigbati a ba ké awọn enia buburu kuro, iwọ o ri i.
35Emi ti nri enia buburu, ẹni ìwa-ika, o si fi ara rẹ̀ gbilẹ bi igi tutu nla.
36Ṣugbọn o kọja lọ, si kiyesi i, kò sí mọ: lõtọ emi wá a kiri, ṣugbọn a kò le ri i.
37Ma kiyesi ẹni pipé, ki o si ma wò ẹni diduro ṣinṣin: nitori alafia li opin ọkunrin na.
38Ṣugbọn awọn alarekọja li a o parun pọ̀; iran awọn enia buburu li a o ké kuro.
39Ṣugbọn lati ọwọ Oluwa wá ni igbala awọn olododo; on li àbo wọn ni igba ipọnju.
40Oluwa yio si ràn wọn lọwọ, yio si gbà wọn, yio si gbà wọn lọwọ enia buburu, yio si gbà wọn la, nitoriti nwọn gbẹkẹle e.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 37: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀