O. Daf 44
44
Adura Ààbò
1ỌLỌRUN, awa ti fi eti wa gbọ́, awọn baba wa si ti sọ fun wa ni iṣẹ́ nla ti iwọ ṣe li ọjọ wọn, ni igbà àtijọ́.
2Bi iwọ ti fi ọwọ rẹ lé awọn keferi jade, ti iwọ si gbin wọn: bi iwọ ti fõró awọn enia na, ti iwọ si mu wọn gbilẹ.
3Nitoriti nwọn kò ni ilẹ na nipa idà ara wọn, bẹ̃ni kì iṣe apá wọn li o gbà wọn; bikoṣe ọwọ ọtún rẹ ati apá rẹ, ati imọlẹ oju rẹ, nitoriti iwọ ni ifẹ rere si wọn.
4Iwọ li Ọba mi, Ọlọrun: paṣẹ igbala fun Jakobu.
5Nipasẹ̀ rẹ li awa o bì awọn ọta wa ṣubu: nipasẹ orukọ rẹ li awa o tẹ̀ awọn ti o dide si wa mọlẹ.
6Nitoriti emi kì yio gbẹkẹle ọrun mi, bẹ̃ni idà mi kì yio gbà mi.
7Ṣugbọn iwọ li o ti gbà wa lọwọ awọn ọta wa, iwọ si ti dojutì awọn ti o korira wa.
8Niti Ọlọrun li awa nkọrin iyìn li ọjọ gbogbo, awa si nyìn orukọ rẹ lailai.
9Ṣugbọn iwọ ti ṣa wa tì, iwọ si ti dojutì wa: iwọ kò si ba ogun wa jade lọ.
10Iwọ mu wa pẹhinda fun ọta wa: ati awọn ti o korira wa nṣe ikogun fun ara wọn.
11Iwọ ti fi wa fun jijẹ bi ẹran agutan; iwọ si ti tú wa ka ninu awọn keferi.
12Iwọ ti tà awọn enia rẹ li asan, iwọ kò si fi iye-owo wọn sọ ọrọ̀ rẹ di pupọ.
13Iwọ sọ wa di ẹ̀gan si awọn aladugbo wa, ẹlẹya ati iyọṣutì-si, si awọn ti o yi ni ka.
14Iwọ sọ wa di ẹni-owe ninu awọn orilẹ-ède, ati imirisi ninu awọn enia.
15Idamu mi mbẹ niwaju mi nigbagbogbo, itiju mi si bò mi mọlẹ.
16Nitori ohùn ẹniti ngàn, ti o si nsọ̀rọ buburu; nitori ipa ti ọta olugbẹsan nì.
17Gbogbo wọnyi li o de si wa; ṣugbọn awa kò gbagbe rẹ, bẹ̃li awa kò ṣe eke si majẹmu rẹ.
18Aiya wa kò pada sẹhin, bẹ̃ni ìrin wa kò yà kuro ni ipa tirẹ;
19Bi iwọ tilẹ ti fọ́ wa bajẹ ni ibi awọn ikõkò, ti iwọ si fi ojiji ikú bò wa mọlẹ.
20Bi o ba ṣepe awa gbagbe orukọ Ọlọrun wa, tabi bi awa ba nà ọwọ wa si ọlọrun ajeji;
21Njẹ Ọlọrun ki yio ri idi rẹ̀? nitori o mọ̀ ohun ìkọkọ aiya.
22Nitõtọ, nitori rẹ li a ṣe npa wa kú ni gbogbo ọjọ; a nkà wa si bi agutan fun pipa.
23Ji! ẽṣe ti iwọ nsùn, Oluwa? dide, máṣe ṣa wa tì kuro lailai.
24Ẽṣe ti iwọ fi pa oju rẹ mọ́, ti iwọ si fi gbagbe ipọnju wa ati inira wa?
25Nitoriti a tẹri ọkàn wa ba sinu ekuru: inu wa dì mọ erupẹ ilẹ.
26Dide fun iranlọwọ wa, ki o si rà wa pada nitori ãnu rẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 44: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.