O. Daf 46

46
Ọlọrun Wà pẹlu Wa
1ỌLỌRUN li àbo wa ati agbara, lọwọlọwọ iranlọwọ ni igba ipọnju.
2Nitorina li awa kì yio bẹ̀ru, bi a tilẹ ṣi aiye ni idi, ti a si ṣi awọn oke nla nipò lọ si inu okun:
3Bi omi rẹ̀ tilẹ nho ti o si nru, bi awọn òke nla tilẹ nmì nipa ọwọ bibì rẹ̀.
4Odò nla kan wà, ṣiṣan eyiti yio mu inu ilu Ọlọrun dùn, ibi mimọ́ agọ wọnni ti Ọga-ogo.
5Ọlọrun mbẹ li arin rẹ̀; a kì yio ṣi i ni idi: Ọlọrun yio ràn a lọwọ ni kutukutu owurọ.
6Awọn keferi nbinu, awọn ilẹ ọba ṣidi: o fọhun rẹ̀, aiye yọ́.
7Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakobu li àbo wa.
8Ẹ wá wò awọn iṣẹ Oluwa, iru ahoro ti o ṣe ni aiye.
9O mu ọ̀tẹ tan de opin aiye; o ṣẹ́ ọrun, o si ke ọ̀kọ meji; o si fi kẹkẹ́ ogun jona.
10Ẹ duro jẹ, ki ẹ si mọ̀ pe emi li Ọlọrun, a o gbé mi ga ninu awọn keferi, a o gbé mi ga li aiye.
11Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakobu li àbo wa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 46: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀