Ifi 1
1
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju ati Ìkíni
1IFIHÀN ti Jesu Kristi, ti Ọlọrun fifun u, lati fihàn fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ohun ti kò le ṣaiṣẹ ni lọ̃lọ; o si ranṣẹ o si fi i hàn lati ọwọ́ angẹli rẹ̀ wá fun Johanu, iranṣẹ rẹ̀:
2Ẹniti o jẹri ọ̀rọ Ọlọrun, ati ẹrí Jesu Kristi, ati ti ohun gbogbo ti o ri.
3Olubukún li ẹniti nkà, ati awọn ti o ngbọ́ ọ̀rọ isọtẹlẹ yi, ti o si npa nkan wọnni ti a kọ sinu rẹ̀ mọ́: nitori igba kù si dẹ̀dẹ.
4JOHANU si ìjọ meje ti mbẹ ni Asia: Ore-ọfẹ fun nyin, ati alafia, lati ọdọ ẹniti o mbẹ, ti o si ti wà, ti o si mbọ̀wá; ati lati ọdọ awọn Ẹmí meje ti mbẹ niwaju itẹ́ rẹ̀;
5Ati lati ọdọ Jesu Kristi, ẹlẹri olõtọ, akọbi ninu awọn okú, ati alaṣẹ awọn ọba aiye. Ẹniti o fẹ wa, ti o si wẹ̀ wa ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa,
6Ti o si ti fi wa jẹ́ ọba ati alufa fun Ọlọrun ati Baba rẹ̀; tirẹ̀ li ogo ati ijọba lai ati lailai. Amin.
7Kiyesi i, o mbọ̀ ninu awọsanma; gbogbo oju ni yio si ri i, ati awọn ti o gún u li ọ̀kọ pẹlu; ati gbogbo orilẹ-ede aiye ni yio si mã pohùnrere ẹkún niwaju rẹ̀. Bẹ̃na ni. Amin.
8 Emi ni Alfa ati Omega, ipilẹṣẹ ati opin, li Oluwa wi, ẹniti o mbẹ, ti o ti wà, ti o si mbọ̀wá, Olodumare.
Ìran Kristi
9Emi Johanu, arakunrin nyin ati alabapin pẹlu nyin ninu wahala ati ijọba ati sũru ti mbẹ ninu Jesu, wà ninu erekuṣu ti a npè ni Patmo, nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati nitori ẹrí Jesu Kristi.
10Mo wà ninu Ẹmí li ọjọ Oluwa, mo si gbọ́ ohùn nla kan lẹhin mi, bi iró ipè,
11O nwipe, Emi ni Alfa ati Omega, ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin: ohun ti iwọ ba si ri, kọ ọ sinu iwe, ki o si rán a si awọn ijọ meje; si Efesu, ati si Smirna, ati si Pergamu, ati si Tiatira, ati si Sardi, ati si Filadelfia, ati si Laodikea.
12Mo si yipada lati wò ohùn ti mba mi sọ̀rọ. Nigbati mo yipada, mo ri ọpá fitila wura meje;
13Ati lãrin awọn ọpá fitila na, ẹnikan ti o dabi Ọmọ enia, ti a wọ̀ li aṣọ ti o kanlẹ̀ de ẹsẹ, ti a si fi àmure wura dì li ẹgbẹ.
14Ori rẹ̀ ati irun rẹ̀ funfun bi ẹ̀gbọn owu, o funfun bi sno; oju rẹ̀ si dabi ọwọ́ iná;
15Ẹsẹ rẹ̀ si dabi idẹ daradara, bi ẹnipe a dà a ninu ileru; ohùn rẹ̀ si dabi iró omi pupọ̀.
16O si ni irawọ meje li ọwọ́ ọtún rẹ̀; ati lati ẹnu rẹ̀ wá ni idà oloju meji mimú ti jade: oju rẹ̀ si dabi õrùn ti o nfi agbara rẹ̀ ràn.
17Nigbati mo ri i, mo wolẹ li ẹsẹ rẹ̀ bi ẹniti o kú. O si fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ le mi, o nwi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru; Emi ni ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin:
18 Emi li ẹniti o mbẹ lãye, ti o si ti kú; si kiyesi i, emi si mbẹ lãye si i titi lai, Amin; mo si ní kọkọrọ ikú ati ti ipo-oku.
19 Kọwe ohun gbogbo ti iwọ ti ri, ati ti ohun ti mbẹ, ati ti ohun ti yio hù lẹhin eyi;
20 Ohun ijinlẹ ti irawọ meje na ti iwọ ri li ọwọ́ ọtún mi, ati ọpá wura fitila meje na. Irawọ meje ni awọn angẹli ìjọ meje na: ati ọpá fitila meje na ti iwọ ri ni awọn ijọ meje.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Ifi 1: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.