Ifi 11

11
Àwọn Ẹlẹ́rìí Meji
1A si fi ifefe kan fun mi ti ó dabi ọpá: o wipe, Dide, si wọ̀n tẹmpili Ọlọrun, ati pẹpẹ, ati awọn ti nsìn ninu rẹ̀;
2Si fi agbala ti mbẹ lode tẹmpili silẹ, má si ṣe wọ̀n ọ; nitoriti a fi i fun awọn Keferi: ilu mimọ́ na li nwọn o si tẹ̀ mọlẹ li oṣu mejilelogoji.
3Emi o si yọnda fun awọn ẹlẹri mi mejeji, nwọn ó si sọtẹlẹ fun ẹgbẹfa ọjọ o le ọgọta ninu aṣọ-ọfọ.
4Wọnyi ni igi oróro meji nì, ati ọpá fitila meji nì, ti nduro niwaju Oluwa aiye.
5Bi ẹnikẹni ba si fẹ pa wọn lara, iná a ti ẹnu wọn jade, a si pa awọn ọtá wọn run: bi ẹnikẹni yio ba si fẹ pa wọn lara, bayi li o yẹ ki a pa a.
6Awọn wọnyi li o ni agbara lati sé ọrun, ti ojo kò fi rọ̀ li ọjọ asọtẹlẹ wọn: nwọn si ni agbara lori omi lati sọ wọn di ẹ̀jẹ, ati lati fi oniruru ajakalẹ arun kọlu aiye, nigbakugba ti nwọn ba fẹ.
7Nigbati nwọn ba si ti pari ẹrí wọn, ẹranko ti o nti inu ọ̀gbun goke wá ni yio ba wọn jagun, yio si ṣẹgun wọn, yio si pa wọn.
8Okú wọn yio si wà ni igboro ilu nla nì, ti a npè ni Sodomu ati Egipti nipa ti ẹmí, nibiti a gbé kàn Oluwa wọn mọ agbelebu.
9Ati ninu awọn enia, ati ẹya, ati ède, ati orilẹ, nwọn wo okú wọn fun ijọ mẹta on àbọ, nwọn kò si jẹ ki a gbé okú wọn sinu isà okú.
10Ati awọn ti o ngbé ori ilẹ aiye yio si yọ̀ le wọn lori, nwọn si ṣe ariya, nwọn o si ta ara wọn lọrẹ; nitoriti awọn woli mejeji yi dá awọn ti o mbẹ lori ilẹ aiye loró.
11Ati lẹhin ijọ mẹta on àbọ na, ẹmí ìye lati ọdọ Ọlọrun wá wọ̀ inu wọn, nwọn si dide duro li ẹsẹ wọn; ẹ̀ru nla si ba awọn ti o ri wọn.
12Nwọn si gbọ́ ohùn nla kan lati ọrun wá nwi fun wọn pe, Ẹ gòke wá ìhin. Nwọn si gòke lọ si ọrun ninu awọsanma; awọn ọtá wọn si ri wọn.
13Ni wakati na ìṣẹlẹ nla ṣẹ̀, idamẹwa ilu na si wó, ati ninu ìṣẹlẹ na ẹdẹgbarin enia li a pa: ẹ̀ru si ba awọn iyokù, nwọn si fi ogo fun Ọlọrun ọrun.
14Egbé keji kọja; si kiyesi i, egbé kẹta si mbọ̀wá kánkán.
Kàkàkí Keje
15Angẹli keje si fun ipè; a si gbọ́ ohùn nla lati ọrun wá, wipe, Ijọba aiye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀; on o si jọba lai ati lailai.
16Awọn àgba mẹrinlelogun nì ti nwọn joko niwaju Ọlọrun lori ítẹ wọn, dojubolẹ, nwọn si sìn Ọlọrun,
17Wipe, Awa fi ọpẹ́ fun ọ, Oluwa Ọlọrun, Olodumare, ti mbẹ, ti o si ti wà, ti o si ma bọ̀; nitoriti iwọ ti gbà agbara nla rẹ, iwọ si ti jọba.
18Inu si bi awọn orilẹ-ède, ibinu rẹ si de, ati ìgba lati dá awọn okú lẹjọ, ati lati fi ere fun awọn iranṣẹ rẹ woli ati awọn enia mimọ́ ati awọn ti o bẹ̀ru orukọ rẹ, ati ẹni kekere ati ẹni nla; ati lati run awọn ti npa aiye run.
19A si ṣí tẹmpili Ọlọrun silẹ li ọrun, a si ri apoti majẹmu ninu tẹmpili rẹ̀: mànamána si kọ, a si gbọ ohùn, ãrá si san, ìṣẹlẹ si ṣẹ̀, yinyín nla si bọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Ifi 11: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀