Rom 11

11
Àánú Ọlọrun Fún Israẹli
1NJẸ mo ni, Ọlọrun ha ta awọn enia rẹ̀ nù bi? Ki a má ri. Nitori Israeli li emi pẹlu, lati inu irú-ọmọ Abrahamu, li ẹ̀ya Benjamini.
2Ọlọrun kò ta awọn enia rẹ̀ nù ti o ti mọ̀ tẹlẹ. Tabi ẹnyin kò mọ̀ bi iwe-mimọ́ ti wi niti Elijah? bi o ti mbẹ̀bẹ lọdọ Ọlọrun si Israeli, wipe,
3Oluwa, nwọn ti pa awọn woli rẹ, nwọn si ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ; emi nikanṣoṣo li o si kù, nwọn si nwá ẹmí mi.
4Ṣugbọn idahun wo li Ọlọrun fifun u? Mo ti kù ẹ̃dẹ́gbãrin enia silẹ fun ara mi, awọn ti kò tẹ ẽkun ba fun Baali.
5Gẹgẹ bẹ̃ si ni li akokò isisiyi pẹlu, apakan wà nipa iyanfẹ ti ore-ọfẹ.
6Bi o ba si ṣepe nipa ti ore-ọfẹ ni, njẹ kì iṣe ti iṣẹ mọ́: bi bẹ̃ kọ́, ore-ọfẹ kì iṣe ore-ọfẹ mọ́. Ṣugbọn biobaṣepe nipa ti iṣẹ́ ni, njẹ kì iṣe ti ore-ọfẹ mọ́: bi bẹ̃ kọ́, iṣẹ kì iṣe iṣẹ mọ́.
7Ki ha ni? ohun ti Israeli nwá kiri, on na ni kò ri; ṣugbọn awọn ẹni iyanfẹ ti ri i, a si sé aiya awọn iyokù le:
8Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ọlọrun ti fun wọn li ẹmí orun: oju ki nwọn ki o má le woran, ati etí ki nwọn ki o má le gbọran, titi o fi di oni-oloni.
9Dafidi si wipe, Jẹ ki tabili wọn ki o di idẹkun, ati ẹgẹ́, ati ohun ikọsẹ, ati ẹsan fun wọn:
10Ki oju wọn ki o ṣokun, ki nwọn ki o má le riran, ki o si tẹ̀ ẹhin wọn ba nigbagbogbo.
11Njẹ mo ni, Nwọn ha kọsẹ̀ ki nwọn ki o le ṣubu? Ki a má ri: ṣugbọn nipa iṣubu wọn, igbala dé ọdọ awọn Keferi, lati mu wọn jowú.
12Ṣugbọn bi iṣubu wọn ba di ọrọ̀ aiye, ati bi ifasẹhin wọn ba di ọrọ̀ awọn Keferi; melomelo ni kíkún wọn?
Ìgbàlà fún Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí Kì Í Ṣe Juu
13Ẹnyin ti iṣe Keferi li emi sa mba sọrọ, niwọnbi emi ti jẹ aposteli awọn Keferi, mo gbé oyè mi ga:
14Bi o le ṣe ki emi ki o le mu awọn ará mi jowú, ati ki emi ki o le gbà diẹ là ninu wọn.
15Nitori bi titanù wọn ba jẹ ìlaja aiye, gbigbà wọn yio ha ti ri, bikoṣe iyè kuro ninu okú?
16Njẹ bi akọso ba mọ́, bẹ̃li akopọ: bi gbòngbo ba si mọ́, bẹ si li awọn ẹ̀ka rẹ̀ na.
17Ṣugbọn bi a ba yà ninu awọn ẹ̀ka kuro, ti a si lọ́ iwọ, ti iṣe igi oróro igbẹ́ sara wọn, ti iwọ si mba wọn pín ninu gbòngbo ati ọra igi oróro na;
18Máṣe ṣe fefé si awọn ẹ̀ka na. Ṣugbọn bi iwọ ba nṣe fefé, iwọ kọ́ li o rù gbòngbo, ṣugbọn gbòngbo li o rù iwọ.
19Njẹ iwọ o wipe, A ti fà awọn ẹ̀ka na ya, nitori ki a le lọ́ mi sinu rẹ̀.
20O dara; nitori aigbagbọ́ li a ṣe fà wọn ya kuro, iwọ si duro nipa igbagbọ́ rẹ. Máṣe gbé ara rẹ ga, ṣugbọn bẹ̀ru:
21Nitori bi Ọlọrun kò ba da ẹ̀ka-iyẹka si, kiyesara ki o máṣe alaida iwọ na si.
22Nitorina wo ore ati ikannu Ọlọrun: lori awọn ti o ṣubu, ikannu; ṣugbọn lori iwọ, ore, bi iwọ ba duro ninu ore rẹ̀: ki a má ba ke iwọ na kuro.
23Ati awọn pẹlu, bi nwọn kò ba joko sinu aigbagbọ́, a o lọ́ wọn sinu rẹ̀: nitori Ọlọrun le tún wọn lọ́ sinu rẹ̀.
24Nitori bi a ti ke iwọ kuro lara igi oróro igbẹ́ nipa ẹda, ti a si lọ́ iwọ sinu igi oróro rere lodi si ti ẹda: melomelo li a o lọ́ awọn wọnyi, ti iṣe ẹka-iyẹka sara igi oróro wọn?
Àánú Ọlọrun Wà fún Gbogbo Eniyan
25Ará, emi kò sá fẹ ki ẹnyin ki o wà li òpe niti ohun ijinlẹ yi, ki ẹnyin má ba ṣe ọlọ́gbọn li oju ara nyin; pe ifọju bá Israeli li apakan, titi kíkún awọn Keferi yio fi de.
26Bẹ̃li a o si gbà gbogbo Israeli là; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ni Sioni li Olugbala yio ti jade wá, yio si yi aiwa-bi-Ọlọrun kuro lọdọ Jakọbu:
27Eyi si ni majẹmu mi fun wọn, nigbati emi o mu ẹ̀ṣẹ wọn kuro.
28Nipa ti ihinrere, ọtá ni nwọn nitori nyin: bi o si ṣe ti iyanfẹ ni, olufẹ ni nwọn nitori ti awọn baba.
29Nitori ailábámọ̀ li ẹ̀bun ati ipe Ọlọrun.
30Nitori gẹgẹ bi ẹnyin kò ti gbà Ọlọrun gbọ́ ri, ṣugbọn nisisiyi ti ẹnyin ri ãnu gbà nipa aigbagbọ́ wọn:
31Gẹgẹ bẹ̃li awọn wọnyi ti o ṣe aigbọran nisisiyi, ki awọn pẹlu ba le ri ãnu gbà nipa ãnu ti a fi hàn nyin.
32Nitori Ọlọrun sé gbogbo wọn mọ pọ̀ sinu aigbagbọ́, ki o le ṣãnu fun gbogbo wọn.
Ìyìn fún Ọlọrun
33Ã! ijinlẹ ọrọ̀ ati ọgbọ́n ati ìmọ Ọlọrun! awamáridi idajọ rẹ̀ ti ri, ọ̀na rẹ̀ si jù awari lọ!
34Nitori tali o mọ̀ inu Oluwa? tabi tani iṣe ìgbimọ rẹ̀?
35Tabi tali o kọ́ fifun u, ti a o si san a pada fun u?
36Nitori lati ọdọ rẹ̀, ati nipa rẹ̀, ati fun u li ohun gbogbo: ẹniti ogo wà fun lailai. Amin.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Rom 11: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀