Rom 16

16
Paulu Kí Ọpọlọpọ Eniyan Ninu Ìjọ Romu
1MO fi Febe, arabinrin wa, le nyin lọwọ ẹniti iṣe diakoni ijọ ti o wà ni Kenkrea:
2Ki ẹnyin le gbà a ninu Oluwa, bi o ti yẹ fun awọn enia mimọ́, ki ẹnyin ki o si ràn a lọwọ iṣẹkiṣẹ ti o nwá ni iranlọwọ lọdọ nyin: nitori on pẹlu ti nṣe oluranlọwọ fun ẹni pipọ, ati fun emi na pẹlu.
3Ẹ kí Priskilla ati Akuila, awọn alabaṣiṣẹ mi ninu Kristi Jesu:
4Awọn ẹniti, nitori ẹmí mi, nwọn fi ọrùn wọn lelẹ: fun awọn ẹniti kì iṣe kiki emi nikan li o ndupẹ, ṣugbọn gbogbo ijọ larin awọn Keferi pẹlu.
5Ẹ si kí ijọ ti o wà ni ile wọn. Ẹ ki Epenetu, olufẹ mi ọwọn, ẹniti iṣe akọso Asia fun Kristi.
6Ẹ kí Maria, ti o ṣe lãla pipọ lori wa.
7Ẹ kí Androniku ati Junia, awọn ibatan mi, ati awọn ẹgbẹ mi ninu tubu, awọn ẹniti o ni iyìn lọdọ awọn Aposteli, awọn ẹniti o ti wà ninu Kristi ṣaju mi pẹlu.
8Ẹ kí Ampliatu olufẹ mi ninu Oluwa.
9Ẹ kí Urbani, alabaṣiṣẹ wa ninu Kristi, ati Staki olufẹ mi.
10Ẹ ki Apelle ẹniti a mọ̀ daju ninu Kristi. Ẹ kí awọn arãle Aristobulu.
11Ẹ kí Herodioni, ibatan mi. Ẹ kí awọn arãle Narkissu, ti o wà ninu Oluwa.
12Ẹ kí Trifena ati Trifosa, awọn ẹniti nṣe lãlã ninu Oluwa. Ẹ kí Persi olufẹ, ti o nṣe lãlã pipọ ninu Oluwa.
13Ẹ kí Rufu ti a yàn ninu Oluwa, ati iya rẹ̀ ati ti emi.
14Ẹ kí Asinkritu, Flegoni, Herma, Patroba, Herme, ati awọn arakunrin ti o wà pẹlu wọn.
15Ẹ kí Filologu, ati Julia, Nereu, ati arabinrin rẹ̀, ati Olimpa, ati gbogbo awọn enia mimọ́ ti o wà pẹlu wọn.
16Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ ki ara nyin. Gbogbo ijọ Kristi kí nyin.
Paulu Ṣe Ìkìlọ̀
17Ará, emi si bẹ̀ nyin, ẹ mã ṣọ awọn ti nṣe ìyapa, ati awọn ti nmu ohun ikọsẹ̀ wá lodi si ẹkọ́ ti ẹnyin kọ́; ẹ si kuro ni isọ wọn.
18Nitori awọn ti o ri bẹ̃ kò sìn Jesu Kristi Oluwa wa, bikoṣe ikùn ara wọn; ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ didùndidùn ni nwọn fi npa awọn ti kò mọ̀ meji li ọkàn dà.
19Nitori igbagbọ́ nyin tàn kalẹ de ìbi gbogbo. Nitorina mo ni ayọ̀ lori nyin: ṣugbọn emi fẹ ki ẹ jẹ ọlọgbọn si ohun ti o ṣe rere, ki ẹ si ṣe òpe si ohun ti iṣe buburu.
20Ọlọrun alafia yio si tẹ̀ Satani mọlẹ li atẹlẹsẹ nyin ni lọ̃lọ. Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa ki o wà pẹlu nyin. Amin.
Àwọn Tí Ó Wà Lọ́dọ̀ Paulu Kí Ìjọ Romu
21Timotiu, alabaṣiṣẹ mi, ati Lukiu, ati Jasoni, ati Sosipateru, awọn ibatan mi, ki nyin.
22Emi Tertiu ti nkọ Episteli yi, kí nyin ninu Oluwa.
23Gaiu, bãle mi, ati ti gbogbo ijọ, ki nyin. Erastu, olutọju iṣura ilu, kí nyin, ati Kuartu arakunrin.
24Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa, ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.
Oore-ọ̀fẹ́
25Njẹ fun ẹniti o li agbara lati fi ẹsẹ nyin mulẹ gẹgẹ bi ihinrere mi ati iwasu Jesu Kristi, gẹgẹ bi iṣipaya ohun ijinlẹ, ti a ti pamọ́ lati igba aiyeraiye,
26Ti a si nfihàn nisisiyi, ati nipa iwe-mimọ́ awọn woli, gẹgẹ bi ofin Ọlọrun aiyeraiye, ti a nfihàn fun gbogbo orilẹ-ède si igbọràn igbagbọ́:
27Ọlọrun ọlọ́gbọn nikanṣoṣo nipasẹ Jesu Kristi li ogo wà fun lailai. Amin.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Rom 16: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀