O. Sol 1

1
1ORIN awọn orin ti iṣe ti Solomoni.
Orin Kinni
2Jẹ ki o fi ifẹnukonu ẹnu rẹ̀ kò mi li ẹnu nitori ifẹ rẹ sàn jù ọti-waini lọ.
3Nitoriti õrun ikunra rere rẹ, orukọ rẹ dabi ikunra ti a tú jade, nitorina ni awọn wundia ṣe fẹ ọ.
4Fà mi, awa o sare tọ̀ ọ: ọba ti mu mi wá sinu iyẹwù rẹ̀: awa o yọ̀, inu wa o si dùn si ọ, awa o ranti ifẹ rẹ jù ọti-waini lọ: nwọn fẹ ọ nitõtọ.
5Emi dú, ṣugbọn mo li ẹwà, Ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, bi awọn agọ Kedari, bi awọn aṣọ-tita Solomoni.
6Máṣe wò mi, nitori pe mo dú, nitori pe õrùn ti bojuwò mi: awọn ọmọ iyá mi binu si mi; nwọn fi mi ṣe oluṣọ ọgba-ajara; ṣugbọn ọgba-ajara temi li emi kò tọju.
7Wi fun mi, Iwọ ẹniti ọkàn mi fẹ, nibiti iwọ nṣọ agutan; nibiti iwọ nmu agbo-ẹran rẹ simi li ọsan; ki emi ki o má ba dabi alãrẹ̀ ti o ṣina kiri pẹlu agbo-ẹran awọn ẹgbẹ́ rẹ.
8Bi iwọ kò ba mọ̀, Iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin, jade lọ ni ipasẹ agbo-ẹran, ki iwọ ki o si bọ́ awọn ọmọ ewurẹ rẹ lẹba agọ awọn aluṣọ-agutan.
9Olufẹ mi, mo ti fi ọ we ẹṣin mi ninu kẹkẹ́ Farao.
10Ẹrẹkẹ́ rẹ li ẹwà ninu ọwọ́ ohun ọṣọ́, ọrùn rẹ ninu ilẹkẹ.
11Awa o ṣe ọwọ́ ohun ọṣọ́ wura fun ọ, pẹlu ami fadaka.
12Nigbati ọba wà ni ibujoko ijẹun rẹ̀, ororo mi rán õrun rẹ̀ jade.
13Idi ojia ni olufẹ ọ̀wọ́n mi si mi; on o ma gbe ãrin ọmu mi.
14Olufẹ mi ri si mi bi ìdi ìtànná igi kipressi ni ọgba-ajara Engedi.
15Wò o, iwọ li ẹwà, olufẹ mi; wò o, iwọ li ẹwà: iwọ li oju àdaba.
16Wò o, iwọ li ẹwà, olufẹ mi, nitõtọ, o wuni: ibusun wa pẹlu ni itura.
17Igi kedari ni iti-igi ile wa, igi firi si ni ẹkẹ́ wa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Sol 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀