2 Peteru Ìfáàrà
Ìfáàrà
Peteru ni ó kọ lẹ́tà yìí ní ìgbà tí ọjọ́ ikú rẹ̀ kò jìnnà mọ́. Ó sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìṣòro tó rí pé kò le káṣẹ̀ nílẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí òun bá lọ tán. Ó gba àwọn Kristiani ní ìyànjú láti máa dàgbà nínú ẹ̀mí, kí wọ́n mọ òtítọ́ ìhìnrere tí kì í ṣe àhesọ bí kò ṣe òtítọ́. Ó kìlọ̀ fún wọn nípa àwọn ayédèrú olùkọ́ tí ó ń sọ òtítọ́ di òbu nípa gbígbé èrò tiwọn ga ju ti ìjọ Ọlọ́run lọ. Ní ìparí, ó tọ́ka sí i pé Kristi ń padà bọ̀ ní ọjọ́ kan láti pa ìlànà àtijọ́ run ní ayé yìí, nítorí náà, a kò gbọdọ̀ gbé ara lé ohun àtijọ́ tó jẹ́ ti ayé.
Ìwé Peteru kejì jẹ́ ìpè sí ìdúró ṣinṣin ní àárín ogunlọ́gọ̀ ìṣòro tó lè mú ènìyàn kúrò nínú òtítọ́. Ayé ń wá ọ̀nà láti pa iṣẹ́ Ọlọ́run tì, ṣùgbọ́n a gbọdọ̀ gbé ogun ti gbogbo ìṣòro nípa gbígbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run, gbígba òtítọ́ gbọ́, fífaradà inúnibíni, gbígba Ọlọ́run gbọ́. Kí a sì máa wo ìpadàpọ̀ Kristi.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìdàgbàsókè nínú ẹ̀mí 1.1-21.
ii. Ìkìlọ̀ nípa àwọn olùkọ́ èké 2.1-22.
iii. Ọ̀rọ̀ ìyànjú tó dá lórí ìpadàpọ̀ Kristi nígbà kejì 3.1-18.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
2 Peteru Ìfáàrà: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.