2 Samuẹli Ìfáàrà

Ìfáàrà
Samuẹli kejì ṣàlàyé Dafidi bí, olóòtítọ́ ẹni tí ó jẹ́ aṣojú ọba tí ó dára. Kí ó tó di àkókò yìí ni a tí ń pé Dafidi ní ọba ni Hebroni nípasẹ̀ ẹ̀yà Juda. Ìjọba Dafidi jẹ́ èyí tí ó dára àti èyí tí ó ní àṣeyege. Ó ṣẹ́gun àwọn Jerusalẹmu láti Jebusi, ó sì sọ ọ́ di ìlú ìjọba rẹ̀ àti ibùgbé rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ ó gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa láti ilé Abinadabu wá sí Jerusalẹmu. Ní abẹ́ àkóso Dafidi, Olúwa bùkún fún orílẹ̀-èdè náà láti máa ṣe rere, pé kí wọn máa ṣẹ́gun ọ̀tá àti kí ó lè máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Dafidi múra láti kọ́ tẹmpili fún Olúwa bí ilé ìjọba rẹ̀, àti bí ààyè fún àwọn ọmọ Israẹli láti máa sìn ín. Ṣùgbọ́n wòlíì Natani sọ fún Dafidi pé òun kọ́ ni yóò kọ́ ilé fún Olúwa àti pé Olúwa ní yóò kọ́ ilé fún Dafidi. Ní ìparí ni wòlíì jẹ́ kí ó yé e pé: ọmọ Dafidi, èyí tí yóò jókòó lórí ìjọba Dafidi, ni yóò ṣe ètò ìjọba Ọlọ́run náà dáradára.
Lẹ́yìn ìṣàpèjúwe ìjọba Dafidi nínú ògo àti àṣeyọrí, ó tún sọ̀rọ̀ nípa ibi tó ṣókùnkùn níbi ìjọba rẹ̀, ó sì tún ṣàlàyé nípa àìlágbára àti ìkùnà rẹ̀. Síbẹ̀ Dafidi sì jẹ́ ọba tí Ọlọ́run fi tọkàntọkàn fẹ́ nítorí tí ó fẹ́ láti mọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì. Ìwé yìí parí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Dafidi tí ó fi ń yin Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà á lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìrètí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kí ó lè mú àwọn ìlérí tí ó tí ṣe pé ọba yóò wá láti ilé Dafidi sẹ.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Dafidi jẹ ọba Juda 1.1–4.12.
ii. Àwọn ọdún àkọ́kọ́ Dafidi lórí ìjọba Israẹli 5.1–10.19.
iii. Ìjọba Dafidi nínú àìlágbára àti ìkùnà 11.1–20.26.
iv. Àwọn ọdún tí Dafidi lò gbẹ̀yìn lórí oyè 21.1–24.25.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

2 Samuẹli Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀