Ìṣe àwọn Aposteli 15:7-9

Ìṣe àwọn Aposteli 15:7-9 YCB

Nígbà tí iyàn sì di púpọ̀, Peteru dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ará, ẹ̀yin mọ̀ pé, láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn nínú yín pé, kí àwọn aláìkọlà lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ìhìnrere láti ẹnu mi, kí wọn sì gbàgbọ́. Ọlọ́run, tí ó jẹ́ olùmọ̀-ọkàn, sì jẹ́ wọn lẹ́rìí, ó fún wọn ni Ẹ̀mí Mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwa. Kò sí fi ìyàtọ̀ sí àárín àwa àti àwọn, ó ń fi ìgbàgbọ́ wẹ̀ wọ́n lọ́kàn mọ́.