Kolose 3
3
Àwọn òfin fún ìgbé ayé ìwà mímọ́
1 Níwọ́n ìgbà tí a ti jí yín dìde pẹ̀lú Kristi ẹ máa ṣàfẹ́rí àwọn nǹkan tí ń bẹ lókè, níbi tí Kristi gbé wà tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 2Ẹ máa ronú àwọn ohun tí ń bẹ lókè kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé. 3Nítorí ẹ̀yin ti kú, a sì fi ìyè yín pamọ́ pẹ̀lú Kristi nínú Ọlọ́run. 4Nígbà tí Kristi, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.
5Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyí jásí ìbọ̀rìṣà. 6Lórí àwọn wọ̀nyí ni ìbínú Ọlọ́run ń bọ̀ wá. 7Ẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbé ayé yín sì jẹ́ apá kan ayé yìí. 8Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ gbọdọ̀ fi àwọn wọ̀nyí sílẹ̀: ìbínú, ìrunú, àrankàn, fífi ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ àti ọ̀rọ̀ èérí kúrò ní ètè yín. 9Ẹ má ṣe purọ́ fún ara yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bọ́ ògbólógbòó ara yín pẹ̀lú ìṣe rẹ̀ sílẹ̀, 10 tí ẹ sì ti gbé ìgbé ayé tuntun wọ̀, èyí tí a sọ di tuntun nínú ìmọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ẹni tí ó dá a. 11Níbi tí kò gbé sí Giriki tàbí Júù, ìkọlà tàbí aláìkọlà, aláìgbédè, ara Skitia, ẹrú tàbí òmìnira, ṣùgbọ́n Kristi ni ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.
12 Nítorí náà, bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, ẹni mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, ìṣoore, ìrẹ̀lẹ̀, inú tútù àti sùúrù. 13Ẹ máa fi ara dà á fún ara yín, ẹ sì máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: bí Kristi ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú. 14Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé.
15Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́. 16 Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́ ọ, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin sí Ọlọ́run ní ọkàn ọpẹ́. 17Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jesu Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run baba nípasẹ̀ rẹ̀.
Àwọn òfin fún agbo ilé Kristi
18 Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa.
19Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fẹ́ràn àwọn aya yín, ẹ má sì ṣe korò sí wọn.
20Ẹ̀yin ọmọ ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín ní ohun gbogbo: nítorí èyí dára gidigidi nínú Olúwa.
21Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọn má bà á rẹ̀wẹ̀sì.
22Ẹ̀yin ẹrú, ẹ gbọ́ ti àwọn olówó yín nípa ti ara ní ohun gbogbo; kì í ṣe ní àrọ́júṣe, bí àwọn aláṣehàn ènìyàn; ṣùgbọ́n ní òtítọ́ inú, ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run: 23 Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa fi tọkàntọkàn ṣe é fún Olúwa, kí í ṣe fún ènìyàn; 24Kí ẹ mọ̀ pé lọ́wọ́ Olúwa ni ẹ̀yin ó gba èrè: nítorí ẹ̀yin ń sìn Olúwa Kristi. 25Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àìṣòdodo, yóò gbà á padà nítorí àìṣòdodo náà tí ó ti ṣe: kò sì ṣí ojúsàájú.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Kolose 3: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.