Daniẹli 3

3
Ère wúrà àti iná ìléru
1Nebukadnessari ọba gbẹ́ ère wúrà kan, èyí tí gíga rẹ̀ tó àádọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, tí fífẹ̀ rẹ̀ tó ẹsẹ̀ mẹ́fà, ó sì gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dura ní agbègbè ìjọba Babeli. 2Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-aládé, àwọn olóyè, àwọn ìgbìmọ̀, àwọn baálẹ̀, àwọn balógun, àwọn onídàájọ́, àwọn olùtọ́jú ìṣúra àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba láti wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀. 3Nígbà náà ni àwọn ọmọ-aládé, àwọn olóyè, àwọn onímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn onídàájọ́ àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba, wọn péjọ láti ya ère tí Nebukadnessari ọba gbé kalẹ̀ sí mímọ́, gbogbo wọn sì dúró síwájú u rẹ̀.
4Nígbà náà ni a kéde kígbe sókè wí pé, “Ohun tí a paláṣẹ fún un yín láti ṣe nìyìí, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo: 5 Bí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò, kí ẹ wólẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀. 6Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ tí kò bá wólẹ̀, kí ó fi orí balẹ̀, kí a ju ẹni náà sínú iná ìléru.”
7Nítorí náà, bí wọ́n ṣe gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè, àti èdè gbogbo wólẹ̀, wọ́n sì fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀.
8Ní àsìkò yìí ni àwọn awòràwọ̀ bọ́ síwájú, wọ́n sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ará Juda. 9Wọ́n sọ fún ọba Nebukadnessari pé, “Kí ọba kí ó pẹ́. 10Ìwọ ọba ti pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin gbọdọ̀ wólẹ̀ kí ó fi orí balẹ̀ fún ère wúrà 11àti ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó foríbalẹ̀, a ó sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú iná ìléru. 12Ṣùgbọ́n àwọn ará Juda kan wà, àwọn tí a yàn láti ṣe olórí agbègbè ìjọba Babeli: Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, wọ́n ò ka ìwọ ọba sí. Wọn kò sin òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”
13Nígbà náà ni Nebukadnessari pàṣẹ ní ìrunú àti ìbínú pé kí a mú Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego wá, wọ́n sì mú wọn wá síwájú ọba. 14Nebukadnessari wí fún wọn wí pé, “Ṣé òtítọ́ ni, Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego wí pé ẹ̀yin kò sin òrìṣà mi àti pé ẹ̀yin kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí èmi gbé kalẹ̀. 15Ní ìsinsin yìí, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, bí ẹ̀yin bá ṣetán láti wólẹ̀ kí ẹ̀yin fi orí balẹ̀ fún ère tí mo gbé kalẹ̀ ó dára. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yìn bá kọ̀ láti sìn ín, lójúkan náà ni a ó gbé e yín jù sínú iná ìléru. Ǹjẹ́, ta ni Ọlọ́run náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”
16Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego dá ọba lóhùn wí pé, “Nebukadnessari, kì í ṣe fún wa láti gba ara wa sílẹ̀ níwájú u rẹ nítorí ọ̀rọ̀ yìí. 17Bí ẹ̀yin bá jù wá sínú iná ìléru, Ọlọ́run tí àwa ń sìn lágbára láti gbà wá kúrò nínú rẹ̀, yóò sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀ rẹ, ìwọ ọba. 18Ṣùgbọ́n tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kí ìwọ ọba mọ̀ dájú wí pé àwa kò ní sin òrìṣà rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”
19Nígbà náà ni Nebukadnessari bínú gidigidi sí Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ojú u rẹ̀ sì yípadà, ó sì pàṣẹ pé, kí wọn dá iná ìléru náà kí ó gbóná ní ìlọ́po méje ju èyí tí wọn ń dá tẹ́lẹ̀, 20ó sì pàṣẹ fún àwọn alágbára nínú ogun rẹ̀ pé, kí wọ́n de Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, kí wọn sì jù wọ́n sínú iná ìléru. 21Nígbà náà ni a dè wọ́n pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn, ṣòkòtò, ìbòrí àti àwọn aṣọ mìíràn, a sì jù wọ́n sínú iná ìléru. 22Nítorí bí àṣẹ ọba ṣe le tó, tí iná ìléru náà sì gbóná, ọwọ́ iná pa àwọn ọmọ-ogun tí wọ́n mú Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego lọ. 23Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego ṣubú lulẹ̀ sínú iná ìléru náà pẹ̀lú bí a ṣe dè wọ́n.
24Nígbà náà ni ó ya Nebukadnessari ọba lẹ́nu, ó sì yára dìde dúró, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ pé, “Ṣe bí àwọn mẹ́ta ni a gbé jù sínú iná?”
Wọ́n wí pé, “Òtítọ́ ni ọba.”
25Ó sì wí pé, “Wò ó! Mo rí àwọn mẹ́rin tí a kò dè tí wọ́n ń rìn ká nínú iná, ẹni kẹrin dàbí ọmọ Ọlọ́run.”
26Nígbà náà, ni Nebukadnessari dé ẹnu-ọ̀nà iná ìléru, ó sì kígbe pé, “Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ìránṣẹ́ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, ẹ jáde, ẹ wá níbi!”
Nígbà náà ni Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego jáde láti inú iná. 27Àwọn ọmọ-aládé, ìjòyè, baálẹ̀, àwọn ìgbìmọ̀ ọba péjọ sí ọ̀dọ̀ ọ wọn. Wọ́n rí i wí pé iná kò ní agbára lára wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò jó wọn lára, bẹ́ẹ̀ ni irun orí wọn kò jóná, àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn kò jóná, òórùn iná kò rùn ní ara wọn rárá.
28Nígbà náà, ni Nebukadnessari sọ wí pé, “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ẹni tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, wọn kọ àṣẹ ọba, dípò èyí, wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ ju kí wọn sìn tàbí foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn. 29Nítorí náà, mo pa àṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, orílẹ̀-èdè tàbí èdè kan tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego kí a gé wọn sí wẹ́wẹ́ kí a sì sọ ilé e wọn di ààtàn; nítorí kò sí ọlọ́run mìíràn tí ó lè gba ènìyàn bí irú èyí.”
30Nígbà náà ni ọba gbé Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego ga ní gbogbo agbègbè ìjọba Babeli.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Daniẹli 3: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀