Deuteronomi Ìfáàrà
Ìfáàrà
Ìwé yìí jẹ́ ìtẹ̀síwájú ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé Numeri. Mose ṣe àtúnwí àwọn májẹ̀mú àti ìlànà Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Israẹli.
Deuteronomi gbé Mose àti gbogbo Israẹli wá sí orí ilẹ̀ Moabu. Ọ̀kan lára ohun tí ó jẹ́ kókó inú ìwé yìí ni pé ó yan olórí tuntun fún wọn. Mose sọ̀rọ̀ ìdágbére rẹ̀ fún wọn láti jẹ́ kí wọn wà ní ìmúrasílẹ̀ láti wọ ilẹ̀ Kenaani. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́ ìsọdọ̀tun àwọn májẹ̀mú. Mose ṣe àtẹnumọ́ àwọn òfin tí ó wúlò fún wọn ní gbogbo ìgbà.
Ìfẹ́ Olúwa sí àwọn ènìyàn rẹ̀ àti ìfẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí ọba tí ó ga jùlọ ni ó pè fún ìfarajì fún Olúwa nínú ìsìn, àti ṣíṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìpè láti kúrò ní Horebu 1.1–1.8.
ii. Ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìtàn 1.6–4.49.
iii. Òfin mẹ́wàá, ìre àti ègún 5.1–7.26.
iv. Ìkìlọ̀ fún Israẹli 8.1–13.18.
v. Ọ̀rọ̀ nípa ìdámẹ́wàá àti ọdún ìdásílẹ̀ 14.1–18.22.
vi. Ọ̀rọ̀ ìfẹ́, òfin ìkọ̀sílẹ̀ àti ìjìyà fún rírú òfin 19.1–28.68.
vii Ọ̀rọ̀ ìyànjú ìgbẹ̀yìn Mose àti ikú rẹ̀ 29.1–34.12.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deuteronomi Ìfáàrà: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.