Eksodu 30:22-25

Eksodu 30:22-25 YCB

OLúWA sọ fún Mose pé, Ìwọ yóò mú ààyò tùràrí olóòórùn sí ọ̀dọ̀ rẹ; ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ṣékélì (kílógírámù mẹ́fà) tí òjìá ṣíṣàn, ìdajì bí ó bá yẹ àádọ́tà-lé-nígba (250) ṣékélì tí kinamoni dídùn, àti kénì dídùn àádọ́tà-lé-nígba (250) ṣékélì, kasia ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ṣékélì—gbogbo rẹ̀ ní ìlànà ṣékélì ibi mímọ́ àti hínì òróró olifi kan (lítà mẹ́rin). Ṣe ìwọ̀nyí ní òróró mímọ́ ìkunra, tí a pò gẹ́gẹ́ bí olùṣe òórùn dídùn tì í ṣe, Yóò jẹ òróró mímọ́ ìtasórí.