Eksodu Ìfáàrà
Ìfáàrà
Ìwé yìí jẹ́ èkejì ìwé tí a fi orúkọ Mose pè. Ó jẹ́ ìtẹ̀síwájú ìwé Gẹnẹsisi. Ó sọ nípa ìsílọ sí ilẹ̀ Ejibiti àti àwọn tí ó bá Jakọbu lọ sí Ejibiti.
Ìwé yìí ní ó jẹ́ kí a mọ orúkọ tí Ọlọ́run fi fi ara rẹ̀ hàn, àbùdá rẹ̀, ìràpadà rẹ̀, òfin rẹ̀ àti bí a ó ti máa sìn ín. Bákan náà ni ó sọ nípa yíyan Mose àti iṣẹ́ rẹ̀. Ó sọ nípa ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àlùfáà àti iṣẹ́ wòlíì. Ó sọ nípa bí májẹ̀mú àtijọ́ ní àárín Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣe wá sí abẹ́ àkóso májẹ̀mú tuntun tí a mọ̀ sí májẹ̀mú Sinai. Ó fún wa ní òye tí ó jinlẹ̀ tí ó sì yè kooro nípa Ọlọ́run. Ohun tí ìwé yìí dojúkọ jù ni òtítọ́ àti ìfarahàn Ọlọ́run bí ó ṣe hàn nípa orúkọ rẹ̀ Yááwè àti nípa ògo rẹ̀. Bákan náà ni ó tẹnumọ́ àwọn àbùdá rẹ̀ bí olùdájọ́, olóòtítọ́, aláàánú, onígbàgbọ́, ẹni mímọ́. Bí a bá mọ orúkọ Ọlọ́run, a gbọdọ̀ mọ́ òun fúnrarẹ̀, àti àwọn àbùdá àti àwọn àkójọpọ̀ ìwà rẹ̀.
Ọlọ́run ni Olúwa ìtàn. Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀. “Ó ga ní mímọ́, ó pọ̀ ní ògo àti ọlá, Ó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu.” Àwọn àjàkálẹ̀-ààrùn ara àwọn ọmọ Israẹli, àti ti ara àwọn ọmọ Ejibiti kò kọjá ìkápá rẹ̀. Ọba Farao, gbogbo ará Ejibiti àti gbogbo ará Israẹli ni ó rí ọwọ́ agbára Ọlọ́run. Ọlọ́run kò gbàgbé gbogbo ìlérí rẹ̀ fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀. Gbogbo ohun tí Ó ti ṣe ní ìlérí fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ń mú ṣẹ lẹ́yìn ìdáǹdè àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní oko ẹrú láti ilẹ̀ Ejibiti, tí ó sì mú wọn lọ sí ilẹ̀ ìlérí. Májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli ní Sinai jẹ́ ìgbésẹ̀ mìíràn fún ìmúṣẹ ìlérí tí Ó ti ṣe fún wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
Ìwé yìí fi ọ̀rọ̀ ìràpadà múlẹ̀ gbọingbọin bí a ti rí i nínú àlàyé tí ó sọ nípa àjọ ìrékọjá. Ó gbé àwọn òfin tó jẹ́ ìpìlẹ̀ Bíbélì lélẹ̀ nínú àwọn òfin mẹ́wàá àti ìlànà ìwé òfin májẹ̀mú, èyí tó ń tọ́ àwọn ọmọ Israẹli ṣọ́nà. Ọlọ́run gbé Mose dìde gẹ́gẹ́ bí olùlàjà láti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìdè kúrò ní oko ẹrú Ejibiti, láti gbé ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ ní àárín wọn nípa mímú wọn lọ sí ilẹ̀ ìlérí àti láti kọ́ ibùgbé rẹ̀ sí àárín àwọn Israẹli.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìmúṣẹ ìlérí ìbísí 1
ii. Ìmúra fún ìtúsílẹ̀ 2.1–4.26.
iii. Ìgbésẹ̀ aṣíwájú 4.27–7.5.
iv. Ìdájọ́ àti ìgbàlà nípasẹ̀ àjàkálẹ̀-ààrùn 7.6–11.10.
v. Àjọ ìrékọjá 12.1-28.
vi. Ìpadàbọ̀ láti Ejibiti 12.29-51.
vii. Ìyàsímímọ́ àkọ́bí 13.1-16.
viii. Líla Òkun pupa kọjá 13.17–15.21.
ix. Ìrìnàjò lọ Sinai 15.22–18.27.
x. Májẹ̀mú Sinai 19–24.
xi. Ìsìn mímọ́ 25–40.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Eksodu Ìfáàrà: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.