Esra Ìfáàrà

Ìfáàrà
Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ rí ìwé Esra àti Nehemiah bí ẹyọ ìwé kan tí ó papọ̀ mọ́ èkínní àti èkejì Kronika. Wọ́n ṣe àtẹnumọ́ àwọn ohun ìtọ́kasí nínú ìwé Esra, èyí tí ó ti gbà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wa. Ó sọ nípa ìpadàbọ̀ àwọn tó lọ ìgbèkùn, bí wọn ṣe pinnu láti tún tẹmpili kọ́, bí àtakò ṣe dìde lórí àtúnkọ́ tẹmpili, àti onírúurú àtúnṣe tí Esra ṣe. Ó sọ nípa àwọn tí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ nínú kíkọ́ ògiri, àwọn tí ó pa májẹ̀mú mọ́ àti ibùgbé Jerusalẹmu àti àwọn ìlú tókù. Bákan náà, a tún rí àwọn ìwé pàtàkì méje-tàbí àkọsílẹ̀ méje èyí tí ó sọ nípa òfin Kirusi.
Gẹ́gẹ́ bí ìfojú inú àtijọ́ wò ó, Esra dé Jerusalẹmu nígbà tí ó di ọdún keje, nígbà tí ó dé ní ọdún Atasasesi kejì. Bí ìwé náà ṣe dúró, Esra dé kí Nehemiah tó dé.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Àwọn ìgbèkùn tí ó kọ́kọ́ dé 1.1–2.70.
ii. Títún Pẹpẹ àti tẹmpili kọ́ 3.1–6.22.
iii. Esra kó àwọn ìgbèkùn mìíràn dé 7.1–10.44.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Esra Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀