Gẹnẹsisi Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ní àtètèkọ́ṣe…, ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo…, ni a fi síde ìwé yìí. Ìwé yìí jẹ́ ìwé ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo nínú ayé. Ọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ayé àti ìtàn ìbẹ̀rẹ̀ ayé ni ó sọ nípa rẹ̀. Ìwé yìí ṣe àfihàn ìgbé ayé àwọn tó gbé ní ilẹ̀ Mesopotamia ní ìgbà àtijọ́. Ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ohun gbogbo, ìtàn ìran, ìkún omi, iṣẹ́ ọnà, ìṣíkiri àwọn ènìyàn, títà àti rírà ilẹ̀, òfin tó jẹ mọ́ àṣà àti iṣẹ́ darandaran.
Gẹnẹsisi sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ayé òun ọ̀run, ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn, Òkun àti òfúrufú, ilẹ̀ àti àwọn ọ̀gbìn orí ilẹ̀, oòrùn àti òṣùpá òun ìràwọ̀, ẹ̀dá inú omi àti ẹ̀dá inú afẹ́fẹ́ òun ẹranko orí ilẹ̀, ẹ̀dá ènìyàn tí ó dá ní àwòrán ara rẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ àti ìràpadà, ìbùkún àti ègún, àwùjọ àti ọ̀làjú, ìgbéyàwó àti níní ìdílé, iṣẹ́ ọnà àti iṣẹ́ ọwọ́.
Gẹnẹsisi jẹ́ ìwé tí ó ṣe pàtàkì púpọ̀, tí ó ń fún ni ní òye nípa àwọn ìwé inú Bíbélì tókù. Ọ̀rọ̀ inú ìwé náà nípọn, ó sì kún fọ́fọ́. Ó sọ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti ayé, Ọlọ́run àti ẹ̀dá ènìyàn, ènìyàn àti ènìyàn. Ó jẹ́ kí ó yé wa pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni orúkọ yìí tọ́ sí. Ó kọ́ wa pé Ọlọ́run tòótọ́ yìí ló jẹ ọba lórí ohun gbogbo. Ó kọ́ wa bí Ọlọ́run ṣe fi ìdí májẹ̀mú rẹ̀ múlẹ̀ ní àárín àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, tí ó sì pinnu ìfẹ́ àti ògo rẹ̀ fún wọn, tí ó sì pè wọ́n níjà láti fi ara wọn fún un. Ó gbé ìrúbọ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i fífi ẹ̀mí fún ẹ̀mí. Bákan náà ni ó ta wá ní olobó pé Ọlọ́run fún wa ní oore-ọ̀fẹ́ láti ní ìràpadà kúrò lọ́wọ́ agbára èṣù.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìṣẹ̀dá ayé 1.1–2.3.
ii. Adamu àti Efa nínú ọgbà Edeni 2.4-25.
iii. Ìṣubú ènìyàn àti ìyọrísí rẹ̀ 3.
iv. Ẹ̀ṣẹ̀ gbilẹ̀ 4.1-16.
v. Àwọn ìran méjì 4.17–5.32.
vi. Ibi tí ẹ̀ṣẹ̀ gbilẹ̀ dé ṣáájú ìkún omi 6.1-8.
vii. Ìkún omi 6.9–9.29.
viii. Ìtànkálẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè 10.1–11.26.
ix. Ìgbé ayé Abrahamu 11.27–25.11.
x. Ìran Iṣmaeli 25.12-18.
xi. Ìgbé ayé Jakọbu 25.19–35.29.
xii. Ìran Esau 36.1–37.1.
xiii. Ìgbé ayé Josẹfu 37.2–50.26.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Gẹnẹsisi Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀