Habakuku Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìwé yìí jẹ́ àsọyé ọ̀rọ̀ láàrín wòlíì àti Ọlọ́run. Habakuku tẹnumọ́ ohun tí ó jẹ ẹ́ lọ́kàn pẹ̀lú Ọlọ́run nípa àwọn àìṣedéédéé tí ó wà ní ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún Habakuku pé àwọn ènìyàn búburú ń gbèrú, ìninilára sì ń gbilẹ̀ ní Juda; ṣùgbọ́n ó wòye pé Olúwa fọwọ́lẹ́rán. Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún un pé Ọlọ́run lo Babeli tí ó jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ láti fi ìyà jẹ Juda tí ó jẹ́ mímọ́ jù wọ́n lọ, bẹ́ẹ̀ ni ojú Ọlọ́run korò láti wo ẹ̀ṣẹ̀. Ipò Israẹli sí Ọlọ́run ni ohun tí ìwé yìí dojúkọ.
Àwọn ohun tí ó jẹ́ kókó inú ìwé yìí dá lórí àwọn ọ̀nà tí a gbà ń tún àwọn òfin rọ láti ṣègbé lẹ́yìn àwọn olódodo sínú ìṣòro. Ọ̀pọ̀ àwọn ìdájọ́ òdodo ni àwọn aláìṣòótọ́ ti yí padà fún ìpalára àwọn olódodo. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n mòòkùn nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọn fi pàṣán ìyà na àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ ti Ọlọ́run. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ ìpayà fún Habakuku, wọ́n ń ru sókè ní ọkàn rẹ̀ ní ìgbà gbogbo. Habakuku ṣe ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ní gbangba (3.1). Ìyanu ló jẹ́ fún Habakuku nígbà tí ó rí i pé ìwà búburú, ìwarùnkì àti ìninilára wọ́n pọ̀jù ní Juda ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń wò wọ́n kò sì ṣe ohunkóhun. Nígbà tí Habakuku gbọ́ wí pé Olúwa ti fẹ́ fà wọ́n tu, ìgbà náà ni ìyàlẹ́nu rẹ̀ dópin. Ní ìgbẹ̀yìn ni Habakuku kọ́ ẹ̀kọ́ pé ó yẹ láti sinmi lé àsìkò Ọlọ́run àti láti dúró dé iṣẹ́ rẹ̀ nínú ìsìn. Èyí ni ó pilẹ̀ ọ̀rọ̀ láàrín wòlíì àti Ọlọ́run.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìráhùn àkọ́kọ́ Habakuku 1.1-4.
ii. Ìdáhùn Ọlọ́run sí ìráhùn Habakuku 1.5-11.
ii. Ìráhùn ẹ̀ẹ̀kejì Habakuku sí Ọlọ́run 1.12–2.1.
iii. Ìdáhùn Ọlọ́run sí ìráhùn ẹ̀ẹ̀kejì Habakuku 2.2-20.
iv. Àdúrà Habakuku 3.1-19.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Habakuku Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀