Isaiah 29
29
Ègbé ni fún ìlú Dafidi
1Ègbé ni fún ọ, Arieli, Arieli,
ìlú níbi tí Dafidi tẹ̀dó sí!
Fi ọdún kún ọdún
sì jẹ́ kí àwọn àkọlùkọgbà àjọ̀dún un rẹ tẹ̀síwájú.
2Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yóò dó ti Arieli
òun yóò ṣọ̀fọ̀ yóò sì sọkún,
òun yóò sì dàbí pẹpẹ ọkàn sí mi.
3Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo;
Èmi yóò sì fi ilé ìṣọ́ yí ọ ká:
èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdó ti ni mi dojúkọ ọ́.
4Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá;
ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀.
Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti ẹnìkan tó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ láti ilẹ̀ jáde wá,
láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹ
yóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́.
5Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná,
agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù.
Lójijì, ní ìṣẹ́jú kan,
6 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò wá
pẹ̀lú àrá, ilẹ̀-rírì àti ariwo ńlá
àti ẹ̀fúùfù líle àti iná ajónirun
7Lẹ́yìn náà,
ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó bá Arieli jà,
tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódi rẹ̀
tí ó sì dó tì í,
yóò dàbí ẹni pé nínú àlá,
bí ìran ní òru
8àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá pé òun ń jẹun,
ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀;
tàbí bí ìgbà tí ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mu omi,
ṣùgbọ́n nígbà tí ó jí, sì wò ó, ó dákú, òǹgbẹ sì ń gbẹ ọkàn rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè
tí ń bá òkè Sioni jà.
9Ẹ bẹ̀rù kí ẹnu kí ó yà yín,
ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ má sì ríran;
ẹ mutí yó kì í ṣe ọtí wáìnì,
ẹ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n, ṣùgbọ́n kì í ṣe ti ọtí líle.
10 Olúwa ti mú oorun ìjìká wá sórí i yín:
ó ti dì yín lójú ẹ̀yin wòlíì;
ó ti bo orí yín ẹ̀yin aríran.
11Fún un yín gbogbo ìran yìí kò yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi èdìdì dì sínú ìwé kíká. Bí ẹ bá sì fún ẹni tí ó lè ka ìwé kíká náà, tí ẹ sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò lè kà á; a ti dì í ní èdìdì.” 12Tàbí bí ẹ bá fún ẹni tí kò lè ka ìwé kíká náà tí ẹ sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n kà.”
13 Olúwa wí pé:
“Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn,
wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn,
ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi.
Ìsìn wọn si mi
ni a gbé ka orí òfin tí àwọn
ọkùnrin kọ́ ni.
14 Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya
àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu
pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu;
ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé,
ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.”
15Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun
láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa,
tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn
tí wọ́n sì rò pé,
“Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?”
16 Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀,
bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀!
Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé
“Òun kọ́ ló ṣe mí”?
Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé,
“kò mọ nǹkan”?
17Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́
a kò ní sọ Lebanoni di pápá ẹlẹ́tù lójú
àti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí aginjù?
18 Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà,
láti inú fìrífìrí àti òkùnkùn
ni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran.
19Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú Olúwa:
àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
20Aláìláàánú yóò pòórá,
àwọn tí ń ṣẹlẹ́yà yóò di àwátì,
gbogbo àwọn tí ó ní ojú ibi ni a ó ké lulẹ̀—
21àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi,
ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní ilé ẹjọ́
tí ẹ fi ẹ̀rí èké dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́.
22Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa, ẹni tí ó ra Abrahamu padà sọ sí ilé Jakọbu:
“Ojú kì yóò ti Jakọbu mọ́;
ojú wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́.
23Nígbà tí wọ́n bá rí i láàrín àwọn ọmọ wọn,
àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi,
wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́,
wọn yóò tẹ́wọ́gbà mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jakọbu
wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Israẹli.
24Gbogbo àwọn tí ń rìn ségesège ní yóò jèrè ìmọ̀;
gbogbo àwọn tí ń ṣe àròyé yóò gba ìtọ́sọ́nà.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isaiah 29: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.