Isaiah 9

9
A bí ọmọ kan fún wa
1 Síbẹ̀síbẹ̀, kò ní sí ìpòrúru kankan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́. Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sebuluni sílẹ̀ àti ilẹ̀ Naftali pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Galili ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà Òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jordani.
2Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn
ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá;
Lórí àwọn tí ń gbé nínú ilẹ̀ òjìji ikú,
ní ara wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí.
3Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá;
wọ́n sì yọ̀ níwájú rẹ
gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkórè,
gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀
nígbà tí à ń pín ìkógun.
4Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Midiani,
ìwọ ti fọ́ ọ túútúú
àjàgà ti ń pa wọ́n lẹ́rù,
ọ̀pá tí ó dábùú èjìká wọn,
ọ̀gọ aninilára wọn.
5Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogun
àti gbogbo ẹ̀wù tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀,
ni yóò wà fún ìjóná,
àti ohun èlò iná dídá.
6Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,
a fi ọmọkùnrin kan fún wa,
ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀.
A ó sì máa pè é ní: Ìyanu
Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára
Baba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà.
7Ní ti ìgbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun.
Yóò jẹ ọba lórí ìtẹ́ Dafidi
àti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo,
nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀,
pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo
láti ìgbà náà lọ àti títí láéláé.
Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ni yóò mú èyí ṣẹ.
Ìbínú Olúwa Sí Israẹli
8Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jakọbu;
Yóò sì wá sórí Israẹli.
9Gbogbo ènìyàn ni yóò sì mọ̀ ọ́n—
Efraimu àti gbogbo olùgbé Samaria—
tí ó sọ pẹ̀lú ìgbéraga
àti gààrù àyà pé.
10Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀
ṣùgbọ́n a ó tún un kọ́ pẹ̀lú òkúta dídán,
a ti gé àwọn igi sikamore lulẹ̀
ṣùgbọ́n igi kedari ní a ó fi dípò wọn.
11Ṣùgbọ́n Olúwa fún àwọn ọ̀tá Resini ní agbára láti dojúkọ wọ́n
ó sì ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè.
12Àwọn ará Aramu láti ìlà-oòrùn àti Filistini láti ìwọ̀-oòrùn.
Wọ́n sì fi gbogbo ẹnu jẹ Israẹli run.
Ní gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò
Ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.
13Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadà
sí ẹni náà tí ó lù wọ́n
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
14Nítorí náà ni Olúwa yóò ṣe ké àti orí àti ìrù
kúrò ní Israẹli,
àti ọ̀wá ọ̀pẹ àti koríko odò ní ọjọ́ kan ṣoṣo,
15Àwọn àgbàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ní orí,
àwọn wòlíì tí ń kọ́ni ní irọ́ ni ìrù.
16Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣì wọ́n lọ́nà
Àwọn tí a sì tọ́ ni a ń sin sí ìparun.
17Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
tàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó,
nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ Ọlọ́run,
ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde.
Síbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò
ọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.
18Nítòótọ́ ìwà búburú ń jóni bí iná,
yóò jó ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún run,
yóò sì rán nínú pàǹtí igbó,
tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi gòkè lọ bí ọ̀wọ́n èéfín ti í gòkè.
19Nípasẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ilẹ̀ náà yóò di gbígbẹ
àwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná,
ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí.
20Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun,
síbẹ̀ ebi yóò sì máa pa wọ́n,
ní apá òsì, wọn yóò jẹ
ṣùgbọ́n, kò ní tẹ́ wọn lọ́rùn.
Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì máa jẹ ẹran-ara apá rẹ̀.
21Manase yóò máa jẹ Efraimu, nígbà tí Efraimu yóò jẹ Manase
wọn yóò parapọ̀ dojúkọ Juda.
Síbẹ̀síbẹ̀, ìbínú un rẹ̀ kò yí kúrò
Ọwọ́ọ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Isaiah 9: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀