Isaiah Ìfáàrà

Ìfáàrà
Isaiah jẹ́ ìwé tí ó fi ìdájọ́ àti ìgbàlà Ọlọ́run hàn. Nítorí Ọlọ́run nìkan ni ó mọ́ jùlọ ní Israẹli, ẹni tí ó ń fi ìyà jẹ ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n tí yóò tún rà wọ́n padà. Nínú gbogbo ìwé yìí, a pe ìdájọ́ Ọlọ́run ní “iná.” Síbẹ̀ ó tún wí pé Ọlọ́run ní àánú fún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì máa ń yọ wọ́n nínú ìnira ìjọba àti ti ẹ̀mí. Bákan náà, nínú ìwé yìí ni a ti rí àsọtẹ́lẹ̀ pé a ó bí ọba kan, ní ìdílé Dafidi, ẹni tí yóò jẹ ọba nínú òdodo àti pé gbogbo orílẹ̀-èdè yóò wọ́ lọ sí òkè mímọ́ Jerusalẹmu.
A sì tún rí i pé, Olúwa pe Messia ní “ìránṣẹ́ mi.” Ó lo ọ̀rọ̀ yìí fún Israẹli bí orílẹ̀-èdè. Ó jẹ́ ki a rí i dájú pé Kristi ló yọ ìran ènìyàn kúrò nínú ìdè ẹ̀ṣẹ̀. Ó di ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà.
Isaiah ṣàlàyé ì bà ṣe pọ̀ tó wà láàrín Ọlọ́run àti Israẹli. Ó kọ àwọn ìyìn (12.1-6 àti 38.10-20), àti ohùn ẹkún ni (64.12). Ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì tí ó yàn láàyò ni kí ó máa ṣe àfiwé ohun ẹlẹ́mìí sí èyí tí kò ní ẹ̀mí. Fún àpẹẹrẹ ó lo: “Àpáta” láti ṣàlàyé Ọlọ́run. Ó tún mẹ́nuba ìwà òmùgọ̀ tí àwọn tó ń bọ òrìṣà ń hù, ó wí pé ojú yóò tì wọ́n. Isaiah tún tọ́ka sí ìbẹ̀rẹ̀ ẹ ìṣẹ̀lẹ̀ ìtàn àwọn Israẹli, pàtàkì jùlọ ìjáde lọ wọn kúrò láti Ejibiti. Ó sì tún pe gbogbo orílẹ̀-èdè sí ìrònúpìwàdà àti sí ìgbàgbọ́ nínú agbára Ọlọ́run.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ọ̀rọ̀ ìbáwí àti ìlérí 1–6.
ii. Àwọn ibi tí a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Aramu àti Israẹli tí ó lòdì sí Juda 7–12.
iii. Ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè 13–23.
iv. Ìdájọ́ àti ìlérí ìjọba Olúwa 24–27.
v. Ègún mẹ́fà: Márùn-ún lórí àwọn aláìgbàgbọ́ Israẹli àti ọ̀kan lórí Asiria 28–33.
vi. Àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn lórí ìdájọ́ àti ìlérí 34–35.
vii. Ìtàn ìran Asiria láti dé ìgbèkùn Babeli 36–39.
viii. Ìtúsílẹ̀ àti ìpadàbọ̀sípò Israẹli 40–48.
ix. Iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti ìpadàbọ̀sípò Israẹli 49–57.
x. Ìtúsílẹ̀ ayérayé àti ìdájọ́ ayérayé 58–66.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Isaiah Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀