Jeremiah Ìfáàrà

Ìfáàrà
Olúwa ló pe Jeremiah fúnrarẹ̀ láti jẹ́ Wòlíì, ó kọ́kọ́ polongo àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ sọ, èyí tí ó sì di mímúṣẹ. A kò rán Jeremiah nítorí àwọn wòlíì èké nìkan, àwọn wòlíì bí i Hananiah àti Ṣemariah. Ó kéde ìbáwí ní ti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọkùnrin orílẹ̀-èdè, ó sì tún bá wọn wí gidigidi ní ti ìwà ìbọ̀rìṣà wọn, èyí tí ó ṣe pé nígbà mìíràn ọmọ wọn ni wọn yóò fi rú ẹbọ sí ọlọ́run àjèjì. Ìdájọ́ náà tún jẹ́ ọ̀kan gbòógì tí Jeremiah kọ nínú ìwé rẹ̀, lóòtítọ́ ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tọ́ka sí ìrònúpìwàdà tí ó jẹ́ tòótọ́ èyí tí ó lè mú ìbínú Ọlọ́run kúrò lórí ẹlẹ́ṣẹ̀. Jeremiah sì ń ṣàfihàn ìfẹ́ Ọlọ́run sí àwọn ènìyàn Juda nígbà gbogbo, àti pé Ọlọ́run ní ìtara púpọ̀ sí ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ohun tí wọ́n jẹ́ sí i. Bákan náà, ó tún kéde ìbànújẹ́ tí yóò wá sórí ìjọba Juda nítorí ìwà ibi àti ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n ó wí pé bí wọ́n bá bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ìlérí àti májẹ̀mú tí Ọlọ́run tí ṣe fún wọn yóò di mímúṣẹ.
Ìwé Jeremiah yìí ló jẹ́ ìwé tó gùn jù nínú Bíbélì, ó ní ọ̀rọ̀ púpọ̀ ju ti àwọn ìwé tókù lọ. Ó jẹ́ ìwé tí ó ní àkọ́sórí tó pọ̀ nínú, ó sì tún ṣẹ̀dá àwọn ọ̀rọ̀ dáradára. Jeremiah ṣe àpètúnpè àwọn ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n orí, irú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí ni idà, ìyàn àti àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn. Gẹ́gẹ́ bí i ti Esekiẹli, Ọlọ́run sọ fún Jeremiah pé kí ó lo àwọn ààmì kan láti fi ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ààmì wọ̀nyí tún jẹ jáde nínú àwọn àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún Jeremiah, bí i kó má ṣe gbé ìyàwó, kò sì gbọdọ̀ bímọ, Olúwa sì lo àwọn ohun tí ó lè rí láti sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún Jeremiah.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìpè láti jẹ́ wòlíì 1.
ii. Ìkìlọ̀ àti ọ̀rọ̀ ìyànjú sí àwọn Juda 2–35.
iii. Ìjìyà àti ṣíṣe inúnibíni sí wòlíì 36–38.
iv. Ìṣubú Jerusalẹmu àti ọ̀rọ̀ ìyànjú wọn 39–45.
v. Ìdájọ́ sí àwọn orílẹ̀-èdè 46–51.
vi. Ìtọ́kasí ìtàn wọn 52.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jeremiah Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀