Johanu 18:25-27

Johanu 18:25-27 YCB

Ṣùgbọ́n Simoni Peteru dúró, ó sì ń yáná. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀?” Ó sì sẹ́, wí pé, “Èmi kọ́.” Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, tí ó jẹ́ ìbátan ẹni tí Peteru gé etí rẹ̀ sọnù, wí pé, “Èmi ko ha rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àgbàlá?” Peteru tún sẹ́: lójúkan náà àkùkọ sì kọ.