Jobu 35
35
Olóòtítọ́ ni Ọlọ́run
1Elihu sì wí pe:
2“Ìwọ rò pé èyí ha tọ́, tí ìwọ wí pé,
òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọ́run?
3Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóò jásí fún ọ,
tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.
4“Èmi ó dá ọ lóhùn
àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ pẹ̀lú rẹ.
5Síjú wo ọ̀run; kí o rí i, kí ó sì
bojú wo àwọsánmọ̀ tí ó ga jù ọ́ lọ.
6Bí ìwọ bá dẹ́ṣẹ̀, kí ni ìwọ fi sẹ̀ sí?
Tàbí bí ìrékọjá rẹ di púpọ̀, kí ni ìwọ fi èyí nì ṣe sí i?
7Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọ fi fún un,
tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?
8Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bí ìwọ;
òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn.
9“Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n mú ni kígbe;
wọ́n kígbe nípa apá àwọn alágbára.
10Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé,
‘Níbo ni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru;
11Tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọn ẹranko ayé lọ,
tí ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’
12Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dáhùn
nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.
13Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ asán;
bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí.
14Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì í rí i,
ọ̀rọ̀ ìdájọ́ ń bẹ níwájú rẹ,
ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè.
15Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nítorí tí ìbínú rẹ̀ kò tí fìyà jẹ ni,
òun kò ni ka ìwà búburú si?
16Nítorí náà ní Jobu ṣe ya ẹnu rẹ̀
lásán ó sọ ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìsí ìmọ̀.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jobu 35: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.