Jobu 4

4
Ọ̀rọ̀ Elifasi: Ọlọ́run kì í fi ìyà jẹ olódodo
1Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani dáhùn wí pé:
2“Bí àwa bá fi ẹnu lé e, láti bá ọ sọ̀rọ̀, ìwọ o ha banújẹ́?
Ṣùgbọ́n ta ni ó lè pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹnu láìsọ?
3Kíyèsi i, ìwọ sá ti kọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn,
ìwọ ṣá ti mú ọwọ́ aláìlera le.
4Ọ̀rọ̀ rẹ ti gbé àwọn tí ń ṣubú lọ dúró,
ìwọ sì ti mú eékún àwọn tí ń wárìrì lera.
5Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọlù ọ́;
ara rẹ kò lélẹ̀.
6Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ
àti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ?
7“Èmi bẹ̀ ọ́ rántí: Ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀?
Tàbí níbo ni a gbé gé olódodo kúrò rí?
8Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń ṣe ìtulẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀,
tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà.
9Nípa ìfẹ́ sí Ọlọ́run wọn a ṣègbé,
nípa èémí ìbínú rẹ̀ wọn a parun.
10Bíbú ramúramù kìnnìún àti ohùn òǹrorò kìnnìún
àti eyín àwọn ẹgbọrọ kìnnìún ní a ká.
11Kìnnìún kígbe, nítorí àìrí ohun ọdẹ,
àwọn ẹgbọrọ kìnnìún sísanra ni a túká kiri.
12“Ǹjẹ́ nísinsin yìí a fi ohun àṣírí kan hàn fún mi,
etí mi sì gbà díẹ̀ nínú rẹ̀.
13Ní ìrò inú lójú ìran òru,
nígbà tí oorun èjìká kùn ènìyàn.
14Ẹ̀rù bà mí àti ìwárìrì
tí ó mú gbogbo egungun mi jí pépé.
15Nígbà náà ni ẹ̀mí kan kọjá lọ ní iwájú mi,
irun ara mi dìde dúró ṣánṣán.
16Ó dúró jẹ́ẹ́,
ṣùgbọ́n èmi kò le wo àpẹẹrẹ ìrí rẹ̀,
àwòrán kan hàn níwájú mi,
ìdákẹ́rọ́rọ́ wà, mo sì gbóhùn kan wí pé:
17‘Ẹni kíkú le jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run,
ènìyàn ha le mọ́ ju Ẹlẹ́dàá rẹ̀ bí?
18Kíyèsi i, òun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,
nínú àwọn angẹli rẹ̀ ní ó sì rí ẹ̀ṣẹ̀.
19Mélòó mélòó àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀,
ẹni tí ìpìlẹ̀ wọ́n jásí erùpẹ̀
tí yóò di rírun kòkòrò.
20A pa wọ́n run láàrín òwúrọ̀ àti àṣálẹ́
wọ́n sì parun títí láé, láìrí ẹni kà á sí.
21A kò ha ké okùn iye wọ́n kúrò bí?
Wọ́n kú, àní láìlọ́gbọ́n?’

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jobu 4: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀