Jona Ìfáàrà

Ìfáàrà
A fi orúkọ wòlíì tó kópa jùlọ nínú ìwé yìí, Jona, pe ìwé yìí. A lérò pé òun náà ni ó kọ ìwé yìí, ní àkókò tí ọba Jeroboamu kejì gba ilẹ̀ rẹ̀ padà lọ́wọ́ ọba alágbára nì, ọba Asiria. Eliṣa nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ fún ọba Israẹli pé yóò borí Damasku (2Ọb 13.14-18), Jona pàápàá ṣe àtúnsọ èyí. Kò pẹ́ tí Ọlọ́run gbé àjàgà ìgbèkùn Israẹli kúrò tí ajá wọ́n tún padà sínú èébì rẹ̀; wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ bí ti àtijọ́, wọ́n ń retí “ọjọ́ Olúwa.”
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ti béèrè bóyá ìwé Jona jẹ́ ìwé ìtàn lásán. Ohun tó fa ìbéèrè bí èyí ni àbùdá ìwé yìí. Bí àpẹẹrẹ “ìtàn ẹja ńlá.” Ìwé yìí ṣe àfiwé ìgbé ayé àwọn wòlíì, àwọn bí i Mose, Samuẹli, Joṣua, Elijah àti Eliṣa. Ìwé Jona ń ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ wòlíì tìkára rẹ̀. Èyí kò yàtọ̀ sí àgbékalẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ tó jẹ mọ́ tí wòlíì Elijah àti Eliṣa èyí tí a lè ri nínú (1, 2 Àwọn ọba). Òǹkọ̀wé yìí ṣe àfúnpọ̀ gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sí ogójì ẹsẹ, ó sì fi ẹsẹ mẹ́jọ mìíràn ṣe àdúrà ọpẹ́, ó jọ ìwé Rutu púpọ̀. Bákan náà, ìwé yìí fi yé wa pé “Ìgbàlà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.” Ìwé yìí fi ìfẹ́ Ọlọ́run sí àwọn ènìyàn rẹ̀ hàn.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Jona kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ 1.1-17.
ii. Ìjìyà àti ìtúsílẹ̀ Jona 2.1–2.10.
iii. Jona lọ sí Ninefe 3.1–3.10.
iv. Ìbínú Jona lórí àánú tí Olúwa fihàn fún Ninefe 4.1-11.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jona Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀