Matiu 1:18-21

Matiu 1:18-21 YCB

Bí a ṣe bí Jesu Kristi nìyìí: Ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrín Maria ìyá rẹ̀ àti Josẹfu, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí Josẹfu ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòtítọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójútì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, angẹli Olúwa yọ sí i ní ojú àlá, ó wí pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má fòyà láti fi Maria ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni. Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”