Nígbà náà ni Peteru wá sọ́dọ̀ Jesu, ó béèrè pé, “Olúwa, nígbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mi, tí èmi yóò sì dáríjì í? Tàbí ní ìgbà méje ni?”
Jesu dáhùn pé, “Mo wí fún ọ, kì í ṣe ìgbà méje, ṣùgbọ́n ní ìgbà àádọ́rin méje.
“Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ ṣe ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbèsè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàárùn-ún (10,000) tálẹ́ǹtì. Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà.
“Nígbà náà ni ọmọ ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ. ‘Ó bẹ̀bẹ̀ pé, mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ.’ Nígbà náà, ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbèsè náà jì í.
“Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún owó idẹ, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé, ‘san gbèsè tí o jẹ mí lójú ẹsẹ̀.’
“Ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’
“Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbèsè náà tán pátápátá. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.
“Nígbà tí olúwa rẹ̀ pè ọmọ ọ̀dọ̀ náà wọlé, ó wí fún un pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, níhìn-ín ni mo ti dárí gbogbo gbèsè rẹ jì ọ́ nítorí tí ìwọ bẹ̀ mi. Kò ha ṣe ẹ̀tọ́ fún ọ láti ṣàánú fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ṣàánú fún ọ?’ Ní ìbínú, olówó rẹ̀ fi í lé àwọn onítúbú lọ́wọ́ láti fi ìyà jẹ ẹ́, títí tí yóò fi san gbogbo gbèsè èyí ti ó jẹ ẹ́.
“Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run yóò sí ṣe sì ẹnìkọ̀ọ̀kan, bí ẹ̀yin kò bá fi tọkàntọkàn dárí ji àwọn arákùnrin yín.”