Numeri 17
17
Ọ̀pá Aaroni rúwé
1 Olúwa sì sọ fún Mose pé, 2“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí o sì gba ọ̀pá méjìlá lọ́wọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ olórí ìdílé ẹ̀yà ìran wọn, kọ orúkọ ènìyàn kọ̀ọ̀kan sí ara ọ̀pá rẹ̀. 3Lórí ọ̀pá Lefi kọ orúkọ Aaroni, nítorí ọ̀pá kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà fún olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan tí yóò jẹ́ orí fún ẹ̀yà ìran kọ̀ọ̀kan. 4Kó wọn sí àgọ́ ìpàdé níwájú ẹ̀rí níbi tí èmi ti ń pàdé yín. 5Ọ̀pá tí ó bá yí jẹ́ ti ẹni tí èmi bá yàn yóò rúwé, èmi yóò sì dá kíkùn gbogbo ìgbà àwọn ọmọ Israẹli sí yín dúró.”
6Nígbà náà Mose bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, àwọn olórí wọn sì fún un ní ọ̀pá méjìlá, ọ̀pá kan fún olórí kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà ìran wọn, ọ̀pá Aaroni sì wà lára àwọn ọ̀pá náà. 7Mose sì fi ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú Olúwa nínú àgọ́ ẹ̀rí.
8 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì Mose wọ inú àgọ́ ẹ̀rí lọ, ó sì rí ọ̀pá Aaroni, tí ó dúró fún ẹ̀yà Lefi, kì í ṣe wí pé ó hù nìkan Ṣùgbọ́n ó rúwé, ó yọ ìtànná, ó sì so èso almondi. 9Nígbà náà ni Mose kó gbogbo àwọn ọ̀pá jáde láti iwájú Olúwa wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wò wọ́n, ẹnìkọ̀ọ̀kan sì mú ọ̀pá tirẹ̀.
10 Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá Aaroni padà wá síwájú ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí ààmì fún àwọn ọlọ̀tẹ̀. Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má ba à kú.” 11Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti páláṣẹ fún un.
12Àwọn ọmọ Israẹli sọ fún Mose pé, “Àwa yóò kú! A ti sọnù, gbogbo wa ti sọnù! 13Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ tabanaku Olúwa yóò kú. Ṣé gbogbo wa ni yóò kú?”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Numeri 17: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.