Numeri 35

35
Ìlú fún àwọn ọmọ Lefi
1 Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní Jordani tí ó rékọjá láti Jeriko, Olúwa sọ fún Mose pé, 2“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti fún àwọn Lefi ní ilẹ̀ láti gbé lára ogún tí àwọn ọmọ Israẹli yóò jogún. Kí ẹ sì fún wọn ní ilẹ̀ lára pápá oko tútù, káàkiri ìlú. 3Nígbà náà, wọn yóò ní ìlú tí wọn yóò gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn, ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú gbogbo ìní wọn.
4“Ilẹ̀ pápá oko tútù káàkiri ìlú tí ẹ ó fi fún àwọn ọmọ Lefi, wíwọ̀n rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbàá ìgbọ̀nwọ́ (1,500) ẹsẹ̀ bàtà láti ògiri ìlú náà. 5Lẹ́yìn náà, wọn ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ẹsẹ̀ bàtà lápá ibi ìhà ìlà-oòrùn ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ẹsẹ̀ bàtà ní ìhà gúúsù, ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àríwá. Pẹ̀lú ìlú ní àárín. Wọn yóò ní agbègbè yìí gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ pápá oko tútù fún ìlú náà.
Ìlú ààbò
6 “Mẹ́fà lára ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi yóò jẹ́ ìlú ibi ìsásí, tí ẹni tí ó bá pa ènìyàn yóò sá sí. Ní àfikún, ẹ fún wọn ní méjìlélógójì (42) ìlú sí i. 7Ní gbogbo rẹ̀, kí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi ní méjì-dínláàádọ́ta (48) ìlú lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn. 8Ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi láti ara ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli jogún, olúkúlùkù kí ó fi nínú ìlú rẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní rẹ̀ tí ó ní. Gba púpọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní púpọ̀ àti díẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní díẹ̀.”
9 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, 10“Sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí ẹ bá rékọjá odò Jordani sí Kenaani, 11Yan àwọn ìlú kan láti jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìlú ìsásí fún yín, kí apani tó pa ènìyàn ní àìmọ̀ máa sálọ síbẹ̀. 12Wọn yóò jẹ́ ibi ìsásí kúrò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí ẹni tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn má ba à kú kí ó tó dúró níwájú àwọn ìjọ àwọn ènìyàn ní ìdájọ́. 13Mẹ́fà nínú ìlú tí ẹ ó fi fún wọn yóò jẹ́ ìlú ààbò fún yín. 14Yan ìlú mẹ́ta ní ìhà ti Jordani, kí ẹ sì yan ìlú mẹ́ta ní ìhà Kenaani tí yóò máa jẹ́ ìlú ìsásí. 15Ìlú mẹ́fà yìí yóò jẹ́ ìlú ìsásí fún àwọn ọmọ Israẹli, fún àjèjì àti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé láàrín wọn, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ sálọ síbẹ̀.
16“ ‘Bí ọkùnrin kan bá fi ohun èlò irin lu ènìyàn tí ó kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pa, apànìyàn náà. 17Tàbí tí ènìyàn bá mú òkúta tí ó lè pa ènìyàn lọ́wọ́ tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pa apànìyàn náà. 18Tàbí tí ènìyàn bá mú ohun èlò igi ní ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì lẹ̀ ẹ́ pa ènìyàn, tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni; pípa ní a ó pa apànìyàn náà. 19Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò pa apànìyàn náà; tí ó bá bá a, yóò pa á. 20Tí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń yan odì pẹ̀lú ìríra tí ẹlòmíràn tàbí ju nǹkan sí i pẹ̀lú èrò, tí ó sì kú. 21Tàbí pẹ̀lú ìjà gbangba lù ú pẹ̀lú ìkùùkuu tí ó sì kú, pípa ni a ó pa ẹni bẹ́ẹ̀; apànìyàn ni. Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò pa apànìyàn náà tí ó bá bá a.
22“ ‘Ṣùgbọ́n bí ó bá fi nǹkan gún un lójijì láìṣọ̀ta, tàbí tí ó sọ ohunkóhun lù ú láìmọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe 23tàbí, láìri, ju òkúta sí tí ó lè pa á, tí ó sì kú, nígbà tí kì í ṣe ọ̀tá rẹ̀, láti ṣe é léṣe, 24Àwọn àpéjọ gbọdọ̀ dájọ́ láàrín rẹ̀ àti olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà. 25Àpéjọ gbọdọ̀ dá ààbò bo ẹni tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn, kí a sì rán an padà lọ sí ìlú ìsásí tí ó ti wá. Ó gbọdọ̀ dúró níbẹ̀ títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú, ẹni tí a fi ààmì òróró yàn.
26“ ‘Ṣùgbọ́n ti ẹni tí a fi sùn kan bá jáde kọjá ààlà ìlú ìsásí tí ó sá sí. 27Tí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ sì ri ní ìta ìlú náà, olùgbẹ̀san lè pa ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn láìjẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn. 28Ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn gbọdọ̀ dúró nínú ìlú ìsásí títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú; lẹ́yìn ikú olórí àlùfáà, ni ó tó lè padà sí ibi tí dúkìá rẹ̀ wà.
29“ ‘Wọ̀nyí ni ó jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún yín ní ìran yín tó ń bọ̀, ní ibikíbi tí ẹ bá ń gbé.
30 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn gbọdọ̀ kú gẹ́gẹ́ bí apànìyàn lórí ìjẹ́rìí àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo. Kì yóò jẹ́rìí sí ẹnìkan láti pa.
31“ ‘Má ṣe gba ohun ìràpadà fún ẹ̀mí apànìyàn, tí ó jẹ̀bi kí ó kú. Ṣùgbọ́n pípa ni kí a pa á.
32“ ‘Má ṣe gba ìràsílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá lọ sí ìlú ìsásí, pe kí ó padà máa gbé ní ilẹ̀ tirẹ̀ kí ó tó di ìgbà ikú olórí àlùfáà.
33“ ‘Má ṣe sọ ilẹ̀ tí ẹ wà di àìmọ́. Ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́. Àtúnṣe kì yóò sí fún ilẹ̀ tí a ti ta ẹ̀jẹ̀ lé lórí, àyàfi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ta á sílẹ̀. 34Má ṣe sọ di àìmọ́, ilẹ̀ tí ẹ ń gbé, àti èyí tí mo ń gbé, nítorí Èmi Olúwa ń gbé láàrín àwọn ọmọ Israẹli.’ ”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Numeri 35: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀