Ìfihàn Ìfáàrà
Ìfáàrà
Ìsọ̀rí ńlá méjì ni ìwé pàtàkì yìí ní, àkọ́kọ́ jẹ́ lẹ́tà sí ìjọ Ọlọ́run méje ní agbègbè Asia (1–3). Ìsọ̀rí kejì jẹ́ oríṣìíríṣìí ìran tó dá lórí ayé àti inúnibíni àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ìpadàbọ̀ Kristi, ìdájọ́ ìkẹyìn, ẹgbẹ̀rún ọdún, àti òkè ọ̀run (4–22). Apá kọ̀ọ̀kan tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn ìran wọ̀nyí ń sọ nípa ìparun tó ń bọ̀ wá sórí ayé nínú ibi tí a tẹ́ ọ̀dọ́-àgùntàn (Jesu) sí. Ohun tó papọ̀ mọ́ra yìí jẹ́ ìran nípa àwọn ènìyàn ajẹ́rìí ikú níwájú Ọlọ́run ní òkè ọ̀run àti àwọn ẹni mímọ́ tí a ṣe inúnibíni sí ní ayé. Ìran náà tẹ̀síwájú sí ìdojúkọ ara ẹni láàrín àwọn àgbèrè obìnrin àti Babeli àti ọ̀rọ̀ ìpè Ọlọ́run, ẹni tó jẹ́ ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn Olúwa (19.16), wá láti pa ẹ̀ṣẹ̀ run àti láti pèsè ààyè fún àwọn Kristiani. Ohun tó tẹ̀lé èyí ni àwọn ìdájọ́ àti ògo pẹ̀lú àdúrà ìparí, “Máa bọ̀ wá Jesu Olúwa. Àmín” (22.20).
Ìwé yìí fi Jesu hàn bí ẹni tí a kẹ́gàn, ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run tí a pa nítorí ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. Ìrètí gbogbo Kristiani ni pé, ní ọjọ́ kan, ohun gbogbo yóò padà bọ́ sí ipò, Ọlọ́run ni yóò jẹ́ ohun gbogbo nínú ohun gbogbo. A ó nu omijé nù, ikú, ìbànújẹ́, ẹkún àti ìrora yóò lọ pátápátá (21.4). Ọ̀rọ̀ ìtùnú yìí wà fún gbogbo Kristiani ní ìgbà gbogbo.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìran tí ó kọ́ wáyé 1.1-20.
ii. Lẹ́tà méje sí àwọn ìjọ Ọlọ́run méje. 2.1–3.22.
iii. Ìran Ọlọ́run àti ọ̀dọ́-àgùntàn. 4.1–5.14.
iv. Èdìdì méje ti ìdájọ́. 6.1–8.5.
v. Ìpè méje ti ìdájọ́. 8.6–11.19.
vi. Ìran ohun ti ayé àti ohun ti ọ̀run. 12.1–14.20.
vii. Ọpọ́n ìdájọ́ méje. 15.1–16.21.
viii. Ìdájọ́ àgbèrè àti Babeli. 17.1–19.21.
ix. Òpin ìran àti ìran tí ń bọ̀. 20.1–22.21.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Ìfihàn Ìfáàrà: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.