Rutu Ìfáàrà

Ìfáàrà
Òǹkọ̀wé yìí dojúkọ ìwà rere àti ìwà ìkónimọ́ra tí Rutu hù sí Naomi àti ìwà rere Boasi sí àwọn opó méjèèjì yìí. Ó fi wọ́n hàn bí àpẹẹrẹ ìgbé ayé ìwà rere nínú iṣẹ́ ojoojúmọ́, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún ìfẹ́ láti mú òfin Ọlọ́run sẹ. Irú ìfẹ́ yìí gan an fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn ní ọ̀nà ìyanu láti lè mú kí ìwà ènìyàn papọ̀ mọ́ tí Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ ìyàlẹ́nu pé, ẹni tí ó fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn gedegbe jẹ́ ará Moabu. Síbẹ̀ gbogbo òtítọ́ rẹ̀ sí ìdílé Israẹli nínú èyí tí a tí gbé e ní ìyàwó àti gbogbo ayé rẹ̀ tí ó fi fún ìyá ọkọ rẹ̀ fi í hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọbìnrin Israẹli tòótọ́ àti ẹrú tí ó yẹ fún ilé Dafidi. Gẹ́gẹ́ bí ìran kan ni ilé Dafidi, ìwé Rutu jẹ́ kí ó yé wa ipa tí ìtàn rẹ̀ kó nínú ìràpadà. Pàtàkì ìwé náà jẹ́ ìtàn ìyípadà Naomi láti ìkorò sí inú dídùn nípasẹ̀ kíkó ènìyàn mọ́ra. Ọlọ́run bùkún ìwà Rutu àti Boasi.
Ìwé Rutu jẹ́ ìtàn kékeré àwọn Heberu, tí a sọ pẹ̀lú ọgbọ́n orí. Ní ìyanu, a mú wọn kúrò nínú ìpọ́njú nípasẹ̀ ìṣípayá mẹ́rin èyí tí ó mú wọn ní ìtúsílẹ̀ àti ìrètí. Àwọn ẹ̀dá ìtàn méjèèjì Rutu àti Boasi. Èkínní jẹ́ ọmọ kékeré àlejò, nígbà tí èkejì jẹ́ ẹni tí ó ti gbọ́njú, ẹni tí ó rí ṣe ní Israẹli, tí ó sì gbilẹ̀ ní ìletò ara a rẹ̀. Ẹni tí ó kọ ìwé Rutu mu ọkàn gbogbo àwọn ènìyàn mọ ìwà Rutu àti Boasi wí pé wọ́n jẹ́ ẹni tó ní ìwà ìkónimọ́ra.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Àìní Naomi 1.1-5.
ii. Naomi padà láti ilẹ̀ Moabu 1.6-22.
iii. Rutu àti Boasi pàdé ní oko ìkórè 2.
iv. Rutu lọ bá Boasi ni ilẹ̀ ìpakà 3.
v. Boasi ń ṣe ètò láti fẹ́ Rutu 4.1-12.
vi. Ìṣesí Naomi 4.13-17.
vii. Ìran Dafidi. 4.12-22.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Rutu Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀