I. Kor 2:10-12
I. Kor 2:10-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣi wọn paya fun wa nipa Ẹmí rẹ̀: nitoripe Ẹmí ni nwadi ohun gbogbo, ani, ohun ijinlẹ ti Ọlọrun. Nitori tani ninu enia ti o mọ̀ ohun enia kan, bikoṣe ẹmí enia ti o wà ninu rẹ̀? bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o mọ̀ ohun Ọlọrun, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun. Ṣugbọn awa ti gbà, kì iṣe ẹmi ti aiye, bikoṣe Ẹmí ti iṣe ti Ọlọrun; ki awa ki o le mọ̀ ohun ti a fifun wa li ọfẹ lati ọdọ Ọlọrun wá.
I. Kor 2:10-12 Yoruba Bible (YCE)
Nǹkan yìí ni Ọlọrun fi àṣírí rẹ̀ hàn wá nípa Ẹ̀mí. Ẹ̀mí ní ń wádìí ohun gbogbo títí fi kan àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọrun. Nítorí ẹ̀dá alààyè wo ni ó mọ ohun tí ó wà ninu eniyan kan bíkòṣe ẹ̀mí olúwarẹ̀ tí ó wà ninu rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn nǹkan Ọlọrun: kò sí ẹni tí ó mọ̀ wọ́n àfi Ẹ̀mí Ọlọrun. Ṣugbọn ní tiwa, kì í ṣe ẹ̀mí ti ayé ni a gbà. Ẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ó fi fún wa, kí á lè mọ àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọrun ti fún wa.
I. Kor 2:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀. Ẹ̀mí á máa wádìí ohun gbogbo, kódà àwọn àṣírí Ọlọ́run tó jinlẹ̀ jùlọ. Ta ni nínú ènìyàn tí ó mọ èrò ọkàn ènìyàn kan, bí kò ṣe ẹ̀mí ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀? Bákan náà, kò sí ẹni ti ó mọ àwọn èrò Ọlọ́run, bí kò ṣe Ẹ̀mí Ọlọ́run fúnrarẹ̀. Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́.